Ọwọ tẹ awọn ọrẹ meta yii kẹkẹ Marwa ni wọn fi n ṣe wan-ṣaansi laarin ilu

Adewale Adeoye

Awọn agba bọ, wọn ni ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, bẹẹ gan-an lo ri fawọn jaguda ọrẹ mẹta kan to jẹ pe wọn ti jingiri ninu lilo kẹkẹ Marwa fi ṣe wan-ṣaansi laarin ilu kan ti wọn n pe ni Rantya, nipinlẹ Plateau. Awọn afurasi ọdaran ọhun ni: Umar Abu, Peter Ezekiel ati Kelvin Monday, ti gbogbo wọn pata n gbe laduugbo Rantya, nipinlẹ Plateau yii kan naa.

ALAROYE gbọ pe wọn ti wa lẹnu iṣẹ naa tipẹ tawọn ọlọpaa agbegbe naa si ti n dọdẹ awọn oniṣẹ ibi naa ko too di pe ọwọ tẹ wọn lasiko ti wọn ja araalu kan lole dukia rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Alfred Alabo, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, sọ pe ṣe lawọn afurasi ọdaran naa maa n gbe kẹkẹ  wọn kaakiri aarin ilu, ti wọn aa si maa wa awọn araalu to fẹẹ wọ kẹkẹ Marwa lọ sibi ti wọn n lọ.

Loju-ẹsẹ ti ero kan tabi meji ba ti wọle sinu kẹkẹ  wọn ni wọn aa ti fi oogun pa wọn lara, lẹyin naa ni wọn aa ja wọn lole dukia wọn. Ati pe foonu igbalode olowo iyebiye lawọn maa n saaba ji lọwọ awọn araalu to ba ṣagbako wọn.

Alukoro ni araalu kan ti wọn ti bọ silẹ lẹyin ti wọn ja a lole laipẹ yii, lo waa fọrọ naa to awọn leti, tawọn si bẹrẹ si i ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ko too di pe ọwọ tẹ wọn laipẹ yii.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita nipa iṣelẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘’Ọwọ wa ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹta kan to jẹ pe kẹkẹ Marwa ni wọn maa n lo fi ṣe wan-ṣaansi laarin ilu, ṣe ni wọn maa n foogun ba awọn to ba fẹẹ wọ kẹkẹ wọn sọrọ ko too di pe awọn yẹn wọle.

‘’Bi wọn ba si ti wọnu kẹkẹ  naa tan ni wọn aa ti ja wọn lole dukia wọn, ṣugbọn ọwọ awọn ọlọpaa agbegbe naa to n dọdẹ wọn pada tẹ wọn, wọn si ti jẹwọ ipa buruku ti wọn n ko laarin ilu naa fawọn ọlọpaa bayii.

Alukoro ni awọn maa too foju wọn bale-ẹjọ, ki wọn le fimu kata ofin fohun ti wọn ṣe.

 

Leave a Reply