Jamiu Abayọmi
Ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan Abawulor Omenka, lọwọ ti tẹ bayii pe ayederu satifikeeti awọn Dokita oniṣegun oyinbo lo n gbe kiri, to si ti lo ayederu iwe naa lati tọju aimọye awọn alaisan ti ko mọ pe ki i ṣe ojulowo dokita.
Ileewe giga fasiti Convenant University Medical Centre, to wa lagbege Sango-Ọta, ipinlẹ Ogun ni wọn gbe iwe sita pe awọn n wa oniṣegun oyinbo to poju owo ti yoo maa tọju awọn ọmọ ileewe ati oṣiṣẹ inu ọgba naa. Ni ayederu dokita naa ba kọwe iwaṣẹ si wọn.
ALAROYE gbọ pe lasiko ifọrọwanilẹnuwo to ko awọn oriṣiiriṣii satifikeeti silẹ ati ẹda iwe-ẹri iṣegun oyinbo to jẹ tọdun 2015, lati fi gbaṣẹ nileewe naa, lọwọ awọn agbarijọ dokita aladaani kan ti wọn n pe ni Association of Nigerian Private Medical Practitioners (ANPMP) ẹka tipinlẹ Ogun ni aṣiri rẹ tu pe ayederu dokita ni.
Ọkunrin naa lo ṣiṣẹ loriṣiiriṣii ileewosan tẹlẹ pẹlu ayederu iwe-ẹri yii. Lara satifikeeti kan to di mẹru wa ni ti Yunifasiti ipinlẹ Benue, nibi ti wọn ti kọ ọ sibẹ pe o ṣetan pẹlu iwe -ẹri onipo keji, (Second Class Upper), ninu iṣegun ati iṣẹ abẹ, (Medicine ati Surgery). Bakan naa lo tun ni iwe-ẹri mi-in, (MDCN) ti nọmba idanimọ rẹ jẹ ti ogoji ọdun sẹyin, toun gan-an ko si ti i ju ọmọ ọdun marundinlogoji lọ. Eyi lo tete mu ifura wa, ṣugbọn lẹyin ti wọn fọrọ po o nifun pọ lo jẹwọ pe awọn kan ni wọn ba oun tẹ iwe-ẹri naa laduugbo Oluwọle, niluu Eko.
Nigba to n fidi ọrọ ọhun mulẹ alaga ẹgbẹ dokita aladaani nipinlẹ Ogun, Kayọde Oyelade, ni ọmọkunrin naa ko nimọ kikun nipa iṣẹ to fẹẹ gba naa, ati pe atamọ-atamọ to n sọ nigba tawọn n ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun un lo pe akiyesi lo jẹ kawọn wo iwe-ẹri to ko wa daadaa, tọwọ fi ba a. Bakan naa lo lawọn tun kan sawọn ileewosan to loun ti ṣiṣẹ ri, ti wọn si fidi ẹ mulẹ pe ki i ṣe dokita, o kan jẹ oluranlọwọ lasan n bẹ.
Oyelade ni, “Eeyan to ba sun mọ awọn eleto iṣegun oyinbo daadaa yoo mọ nnkan ti mo n sọ pe wọn ki i kọ ipo tabi ami to ba fi yege si satifikeeti wa, wọn aa kan kọ ọ pe o yege ni, eyi si fi han pe feeki ni iwe-ẹri naa.
“Bakan naa lo tun mu ti MDCN wa, nigba ti gbogbon wa ri i, a kan ku sẹrin-in ni, tori pe nọmba ara rẹ ni 11,641, koda emi ti mo ti ṣetan nileewe lati ọdun mejilelọgbọn gan-an, nọmba temi ni 20,815, o si loun ṣetan lọdun 2015, o tumọ si pe o ṣiwaju mi pari ile-iwe, ohun ti nọmba rẹ tumọ si ni pe o pari lati bii ogodi ọdun sẹyin lo ti ṣetan, eyi to fi han pe feeki ni awọn iwe-ẹri naa.”
Agba Dokita naa kadii ọrọ rẹ nilẹ pe awọn ti fa a le ọlọpaa teṣan Onipanu, lagbegbe Ọta, nipinlẹ naa lọwọ, ti wọn yoo si foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ, eyi yoo si jẹ ẹkọ fawọn to ku nidii iru iṣẹ laabi yii.