Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ayederu ọlọpaa meji lọwọ awọn sọja bareke Ọwẹna, to wa niluu Akurẹ, tẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pẹlu ọkọ Toyota Sienna kan to kun fọfọ fun igbo.
Awọn oniṣowo igbo ọhun, Nze Ezenwa, ẹni ọdun marundinlọgọta, ati Stephen Sunday to jẹ ọmọ ọdun marundinlogoji, lọwọ tẹ nijọba ibilẹ Ọwọ, lasiko ti wọn n gbiyanju ati ṣe fayawọ ọpọlọpọ oogun oloro ọhun lọ siluu Abuja.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ṣe lawọn afurasi ọdaran naa mura gẹgẹ bii ọlọpaa, wọn lẹ ayederu nọmba to jẹ ti ileesẹ ọlọpaa mọ ọkọ wọn, bẹẹ ni wọn tun gbe fere ya-fun-un lori ọkọ naa kawọn ẹsọ alaabo ma baa fura si wọn.
Apo igbo mejilelaaadoje (132), foonu mẹrin, ọkọ meji ati owo to to bii ẹgbẹrun mejidinlaaadọjọ naira (#148, 000) ni wọn ba ni ikawọ awọn afurasi ọhun.
Ninu ọrọ soki to ba’wọn oniroyin sọ, ọkan ninu awọn oniṣowo igbo ọhun, Stephen Sunday, ni iṣẹ awakọ loun n ṣe tẹlẹ ki awọn eeyan kan too fi ẹtan fa oun wọ inu okoowo igbo siṣe.
O ni oju ọna oko kan niluu Ọwọ ni wọn ti da awọn duro, ti wọn si bẹ oun lọwẹ lati ba wọn ko ọja naa lọ fun ẹnikan l’Abuja.
Awọn afurasi mejeeji atawọn ẹru ofin ti wọn ba lọwọ wọn lawọn sọja ti fa le ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun oloro ẹka tipinlẹ Ondo lọwọ fun igbesẹ to yẹ.