Faith Adebọla, Eko
Surakat Toheeb, gende ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, tawọn eeyan mọ si Eleweedu, ati ọrẹ ẹ, Sọdiq Muftau, ti wọn n pe ni Mainama, ti wa lakolo ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ Eko bayii, nibi ti wọn n ti n ṣalaye ọna ti ibọn, ọta ibọn ati igbo ti wọn ka mọ wọn lọwọ gba de apo wọn.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan-an to lọ yii, lọwọ palaba awọn mejeeji segi, nigba tawọn ọlọpaa ka wọn mọ laṣaalẹ ọjọ naa.
Gẹgẹ bii alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin ṣe ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹwaa yii, o lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Badagry ti wọn n ṣe patiroolu kiri lagbegbe Ajara, ni wọn kẹẹfin awọn afurasi ọdaran yii, wọn ṣakiyesi pe irin wọn mu ifura lọwọ, ni wọn ba sun mọ wọn, ṣugbọn bi wọn ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn ti bẹ lugbẹ, awọn ọlọpaa naa si mu wọn le. Nigbẹyin, ọwọ tẹ Eleweedu ati Mainama.
Nigba ti wọn yẹ ara wọn wo, ibọn agbelẹrọ oloju-meji kan ni wọn ba, wọn tun ri katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹsan-an, oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii, ati egboogi oloro ti wọn n pe ni igbo lapo wọn.
Ni teṣan, awọn mejeeji jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ lawọn, wọn ni Badagry lawọn n gbe. Amọ nigba ti wọn beere ibi ti wọn ti ri ibọn ati igbo, niṣe ni wọn n wolẹ ṣuu, wọn o ti i jẹwọ.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Abiọdun Alabi, ti lawọn maa ṣewadii to lọọrin nipa wọn, awọn si maa wa awọn ẹlẹgbẹ wọn to sa lọ lawaari.
O nile-ẹjọ lọrọ wọn maa kangun si laipẹ.