Faith Adebọla
Aṣiri iwa ọdalẹ, agbẹyin-bẹbọjẹ ti ọkan ninu awọn ṣọja ilẹ wa hu ti tu, ọwọ ti tẹ ṣọja ti wọn porukọ ẹ ni Emmanuel Lorliam ọhun, ọta ibọn rẹpẹtẹ ni wọn ka mọ ọn lọwọ to we mọ eti ṣokoto awọtẹlẹ rẹ, afi bii igba tawọn obinrin di bebe sidii lo fi kinni ọhun ṣe.
Ba a ṣe gbọ, wọn ni ọkan lara awọn ọmoogun amuṣẹya to n koju awọn afẹmiṣofo lapa Oke-Ọya Naijiria, iyẹn awọn ọmoogun156 Task Force Batallion, ti wọn fun lorukọ Ọpureṣọn Hadin Kai, ni afurasi ọdaran yii.
Ilu Minok, to jẹ sẹkiteria ijọba ibilẹ Kaga, nipinlẹ Borno, lọwọ ti tẹ jagunlabi. Awọn ṣọja ẹlẹgbẹ rẹ ni wọn fura si baagi to gbe lọwọ nigba to wa si ojuko ibi tawọn ọmoogun ọhun ti n sinmi, ti wọn si maa n ko nnkan ija wọn pamọ si, wọn lo loun waa paarọ aṣọ, koun le tete pada soju ija, ṣugbọn lẹyin to ti lọ, wọn fura si baagi dudu to gbe dani, wọn ni irinsi rẹ naa gba ifura, ni wọn ba le e mu.
Ninu fidio to gori ẹrọ ayelujara nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa yii, nibi ti wọn ti ṣafihan bi wọn ṣe n yẹ ara ọmoogun ọdalẹ yii wo, wọn ba awọn ọta ibọn ninu baagi rẹ. Nigba ti wọn tun fi ọbẹ rẹ eti ṣokoto awọtẹlẹ rẹ to wu gbẹndu yika wo, niṣe lawọn ọta ibọn bẹrẹ si i da silẹ bii ọwara ojo, bẹẹ lo ko awọn ẹsibiiti ọhun yika ṣokoto naa.
Ṣa, wọn ni Emmanuel ti jẹwọ pe niṣe loun n ko awọn nnkan ija oloro naa lọọ ta fawọn Boko Haram, oun o si ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ.
Wọn lọkunrin naa yoo kawọ pọnyin rọjọ niwaju igbimọ onidaajọ ti ileeṣẹ ologun ilẹ wa, gẹgẹ bii ilana iṣẹ wọn, ibẹ ni wọn ti maa da sẹria to tọ fun un.