Adewale Adeoye
Nitori gbese miliọnu kan Naira ti baale ile kan, Ọgbeni Ẹnitan Awoyẹmi, ẹni ọdun mọkanlelogoji, jẹ ti ko si mọ bi yoo ṣe san an lo fi dọgbọn sọrọ ara ẹ. Niṣe lo ji ara rẹ gbe, to si ni awọn ajinigbe lo ji oun, lo ba tun n beere fun owo itusilẹ.
Ni bayii, ọdọ awọn ẹṣọ alaabo ipinlẹ Ogun ti wọn n pe ni ‘Ogun State Security Network Agency, tawọn eeyan mọ si Amọtekun, ni baale ile naa wa to ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan an.
ALAROYE gbọ pe nitori gbese miliọnu kan Naira ti afurasi ọdaran naa jẹ lo ṣe parọ pe awọn ajinigbe kan ti ji oun gbe, iyawo rẹ, Abilekọ Tọpẹ Awoyẹmi, ti wọn jo n gbe lagbegbe Irolu-Rẹmọ, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ, nipinlẹ Ogun, lo lọọ fiṣẹlẹ ijinigbe ọhun to awọn Amọtekun to wa lagbegbe naa leti lọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ. O ṣalaye fun wọn pe awọn ajinigbe kan ti ji ọkọ oun gbe sa lọ, miliọnu marun-un Naira ni wọn si n beere fun ko too di pe wọn yoo ju u silẹ.
Loju-ẹsẹ tawọn Amọtekun gbọ si iṣẹlẹ naa ni wọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii.
Ọga agba ajọ Amọtẹkun naa, Ajagun-fẹyinti Alade Adedigba, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii, sọ pe iwadii ijinlẹ tawọn ṣe nipa iṣẹlẹ ọhun fi han gbangba pe tẹtẹ ni afurasi ọdaran naa fowo ta, nitori ko mọ bo ṣe maa san gbese to jẹ pada lo ṣe dọgbọn ji ara rẹ gbe.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘‘O fowo olowo ta tẹtẹ ni, o si ti jẹ gbese miliọnu kan Naira, ṣaaju akoko to jẹ gbese naa lo jẹ pe o ti figba kan jẹ miliọnu mẹfa Naira nidii tẹtẹ naa, o si fowo ọhun ra mọto akero Toyota Corolla kan ati ọkada Bajaj kan.
‘’Tẹtẹ naa ti wọ ọ lẹwu debii pe ko mọ’gba to jẹ gbese miliọnu kan Naira nidii rẹ. Lo ba parọ pe wọn ji oun gbe sa lọ ni. Ninu iwadii ta a ṣe la ti wa a lọ sagbegbe Ijagba, ko si nibẹ, la ba wa a lọ si Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, nipinlẹ Ogun yii kan naa. A ri i ni paaki awọn ọlọkada kan laaarọ kutukutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, la ba fọwọ ofin mu un. Lasiko ta a gba a mu, ṣe lẹnu rẹ n run bii pe o ti gbe nnkan jẹ, o fẹẹ gbẹmi ara rẹ.
Kia la gbe e lọ sileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Rufina Private Hospital, to wa lagbegbe Iperu, fun itọju to peye.
Adedigba ni to ba ti gbadun daadaa lawọn maa fa a le awọn ọlọpaa ipinlẹ naa lọwọ fun igbesẹ to ba yẹ.