Ọwọ tẹ Gboyega, obinrin alarun ọpọlọ lo fipa ba lo pọ ninu oko l’Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kootu Majisireeti to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, lọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan ti wọn porukọ rẹ ni Gboyega Awoyinka ti n jẹjọ lori ẹsun pe o fipa ba obinrin alarun ọpọlọ kan, Rhoda Adeboye, lo pọ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Gboyega to yan iṣẹ agbẹ ati ọkada ṣiṣe laayo lo ki iyawo ile to ti to bii ẹni ọdun mọkandinlogoji naa mọlẹ, to si fipa ba a sun ninu oko koko kan labule Kajọla-Ojurin, eyi to wa nitosi ilu Ọrẹ, lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Awọn ẹsun ti wọn ka si afurasi ọdaran ọhun lẹsẹ ni Agbefọba, Jimmy Amuda, ni o ta ko abala ọtalelọọọdunrun din mẹta (357) ati ọtalelọọọdunrun din meji (358) ninu iwe ofin ti ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Nigba ti wọn si beere lọwọ olujẹjọ boya o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi, o ni oun ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun mejeeji ti wọn fi kan oun.

Lẹyin eyi ni agbẹnusọ fun ijọba bẹbẹ fun sisun igbẹjọ siwaju, ko le lanfaani lati fi awọn iwe ẹsun naa ṣọwọ si ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran, agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni V. A. Akinfẹ, ko si ta ko aba ọhun.

Ninu ipinnu rẹ, Onidaajọ B. A. Ikusika paṣẹ ki afurasi ọhun ṣi lọọ maa gba atẹgun ninu ọgba atunṣe to wa niluu Okitipupa, titi ti ile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba.

 

Ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni adajọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply