Florence Babaṣọla
Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin ẹni ogun ọdun, Hammed Muhammed, to jẹ ọkan lara awọn Fulani ti wọn n ji awọn arinrin-ajo gbe niluu Waasinmi, loju-ọna Ifẹ si Ibadan.
Hammed, ẹni ti ko gbọ ede Yoruba rara, fi ede oyinbo diẹ to gbọ sọ orukọ rẹ fun ALAROYE, o ni ilu Sokoto loun ti wa, ati pe Fulani darandaran loun koun too dara pọ mọ iṣẹ ijinigbe.
Nigba ti Kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, n ṣafihan rẹ, o ṣalaye pe lọjọ kẹfa, oṣu kẹta, ọdun yii, lawọn kan lọ si agọ ọlọpaa agbegbe Ikire lati sọ fun wọn nipa iṣẹlẹ ijinigbe kan to waye ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ naa.
Ọlọkọde sọ siwaju pe, “Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ alaabo yooku fọn sinu igbo lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe ọhun. Bi Hammed ṣe ri wọn lo doju ibọn barẹẹli kọ wọn, ṣugbọn ko pẹ rara ti agbara rẹ fi pin, ti wọn si ri i mu ninu igbo Waasinmi/Ẹgbu.
“Gbogbo awọn ti wọn jọ ṣiṣẹ yẹn ni wọn ti sa lọ, ṣugbọn a ri awọn ti wọn ji gbe gba kalẹ lalaafia lai si ifarapa kankan. Hammed ti jẹwọ pe loootọ lawọn n ṣiṣẹ ijinigbe loju ọna yẹn, lẹyin iwadii, yoo foju bale-ẹjọ.
“Lara awọn nnkan ti a ri gba lọwọ rẹ ni ibọn barẹẹli kan ati ile-ikọta si mẹta.”
Ọlọkọde waa lo asiko ọhun lati kilọ fun awọn ajinigbe ti wọn ti fẹẹ sọ ipinlẹ Ọṣun di ibuba wọn lati so ewe agbejẹẹ mọwọ, tabi ki wọn kuku kuro nitosi oun nitori ikoko ko ni i gba omi ko tun gba ẹyin.