Faith Adebọla
Lẹyin wakati diẹ ti wọn mu ẹnikan to fẹẹ fowo ra ibo l’Ekoo, ọwọ awọn agbofinro ti tun tẹ afurasi arufin kan, Hassan Ahmad, miliọnu meji Naira ni wọn ba lọwọ ẹ, o si ti jẹwọ pe oloṣelu kan lo fowo ọhun ran oun niṣẹ lati lọọ ha a fawọn oludibo.
Alukoro ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lẹnu iṣẹ ọba atawọn iwa aitọ to jẹ mọ ọn, Independent Corrupt Practices and Other Related Offenses Commission (ICPC), Abilekọ Azuka Ogugua lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin, o ni irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji yii, lọwọ tẹ ọkunrin naa, awọn ṣọja ikọ 33 Artillery Brigade ti wọn n pese aabo lagbegbe Alkaleri, nipinlẹ Bauchi ni wọn mu un.
Wọn ni inu baagi “Ghana must go” kan lo ko awọn owo naa si, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun Naira (N900,000) lara owo naa jẹ owo tuntun tawọn araalu lawọn o ri gba taara ni banki, nigba ti miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira jẹ owo atijọ, bọndu mẹfa ni wọn di owo naa si nisalẹ baagi to ko o si, o si ko aṣọ le e lori kawọn eeyan ma baa fura.
Nigba ti wọn da ọkọ ayọkẹlẹ Hilux rẹ to ni nọmba JMA 85 AZ duro, ti wọn si ṣayẹwo si i laṣiiri tu, bẹẹ niṣe lo lẹ nnkan dudu mọ gbogbo gilaasi ọkọ naa eyi to mu ki inu rẹ ṣokunkun dudu.
Ṣa, wọn ti fa afurasi ọdaran yii le awọn ẹṣọ ICPC lọwọ, awọn naa si ti ṣewadii, wọn lọkunrin naa jẹwọ pe ọdọ oloṣelu kan nipinlẹ Gombe loun n ko owo naa lọ, o ni wọn fẹẹ ha a fawọn oludibo ni.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii, gẹgẹ bi wọn ṣe wi.