Ọwọ tẹ iyaale ile yii, ẹran ẹlẹran lo n ji laarin ilu

Adewale Adeoye

Wọn ti mu iyaale ile kan to ti bimọ meji, ṣugbọn ti ko si nile ọkọ to lọọ ji ẹran ewurẹ gbe laarin ilu Gboko, nipinlẹ Benue.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Gboko, nipinlẹ Benue. Awọn ọdọ ilu naa ni wọn fọwọ lile mu un lakooko to ji ẹran ẹlẹran gbe. Wọn tiẹ tun fẹsun kan an pe o pẹ to ti maa n ṣiṣẹ laabi ọhun kọwọ too tẹ ẹ laipẹ yii, ati pe bo ṣe n ji ewurẹ laduugbo, bẹẹ lo n ji ẹran obukọ gbe.

Ṣa o, awọn kọọkan ti wọn gbọ nipa iwa palapala ti iyaale ile naa hu ti n ba a kaaanu ti wọn si n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe nigba ti ko si nile ọkọ mọ ati pe bi ilu ṣe le koko bii oju ẹja lo ṣokunfa bi obinrin naa ṣe lọọ ṣiwa-hu lawujọ. Awọn kọọkan tiẹ n gbe e pooyi ẹnu pe awọn maa ran an lọwọ bo ba bọ ninu ẹsun ti wọn fi kan an yii.

 

Leave a Reply