Ikọ ọtelẹmuyẹ ẹka ileesẹ aabo ẹni laabo ilu, Nigeria Security and Civil Defence Corps, (NSCDC), ti mu awọn ọkunrin meji kan, Ya’u Muhammed, ẹni ọdun marundinlaaadọrin, to wa lati ijọba ibilẹ Warji, nipinlẹ Bauchi, ati Lamido Usman, toun jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, to wa lati ipinlẹ Taraba, ti wọn jingiri ninu nina ayederu owo Naira ati dọla fawọn eeyan, ti wọn yoo si fi gba owo gidi lọwọ wọn.
Niṣe ni wọn maa n dibọn bii awọn to n paarọ owo, ti wọn yoo si fi ọgbọn jibiti gba awọn eeyan nipa kiko owo ayederu fun wọn.
Alukoro ileeṣẹ naa, DCC Oluṣọla Odumosu, ṣalaye fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla yii, ni ọfiisi wọn to wa niluu Abuja pe, o ti to bii ọdun mẹwaa tawọn eeyan naa ti wa lẹnu iṣẹ buruku yii.Ọja kan ti wọn n pe ni ‘Heart Plaza’, to wa ni Mararaba, labẹ biriiji kan to wa ni Karu, nipinlẹ Nasarawa, lọwọ ti tẹ wọn.
Oluṣọla ni aimọye awọn eeyan ni wọn ti lu ni jibiti ọpọlọpọ miliọnu Naira. Nibi ti awọn eeyan naa sa pamọ si lo ni awọn ti lọọ hu wọn jade. Ọkunrin yii ni ohun ti wọn maa n ṣe ni pe wọn yoo ni awọn n ṣẹ owo Naira si dọla, bẹẹ lawọn tun n ṣẹ dọla si Naira. Ṣugbọn ayederu ni wọn maa ko fun wọn.
Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ yii lo dibọn pe oun fẹẹ ṣẹ ẹgbẹrun lọna ọtalerugba o din mẹwaa (250,000) Naira si owo dọla, ni wọn ba ko ayederu fun un.
Ọgọrun-un kan owo dọla to jẹ ojulowo, kaadi ti wọn fi n gbowo (ATM) ati suku draifa ni wọn gba lọwọ wọn.
Olusọla ni awọn ti n fi ọrọ po wọn nifun pọ lati mọ bi wọn ti n ṣiṣẹ naa atawọn nnkan mi-in to yẹ lati mọ.