Ọlawale Ajao, Ibadan
Ori lo ko awọn ero inu ọkọ kan yọ n’Ibadan lonii, ọkọ ero ni wọn wọ ni garaaji Eko to wa laduugbo Iwo Road, n’Ibadan, lai mọ pe awọn ajinigbe lo waa fi mọto ọhun gbero nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe garaaji ti wọn ti n wọkọ Ikọtun (Eko) laduugbo Iwo Road, n’Ibadan, lawọn ero naa ti wọkọ Eko, ọtọ lọna ti dẹrẹba mori le. Nigba ti awọn ero inu ọkọ yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti ba ara wọn l’Akinyẹle, agbegbe ti oriṣiiriṣii ipaniyan ti n ṣẹlẹ n’Ibadan lẹnu ọjọ mẹta yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn ero to n ti ile ọdun bọ pọ ni garaaji ọhun lonii, eyi ni ko jẹ ki awọn alaṣẹ garaaji naa maa tọpinpin awọn awakọ to n ko ero nibẹ, bi dẹrẹba kan ba ti debẹ lati gbero, wọn ki i yẹ wọn lọwọ ẹ wo nigba ti iru ẹni bẹẹ ba ti fun wọn lowo.
Bi awọn ero inu ọkọ ẹlẹni mẹrinla yii ṣe wọkọ ni garaaji ọhun pẹlu ifọkanbalẹ ree lai mọ pe ajinigbe lo gbe ọkọ wa si garaaji naa lati gbero.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ọkan ninu awọn tori ko yọ ninu ewu naa, Abilekọ Sulaiman Rukayat Babayọde, ṣalaye pe “a de garaaji Iwo Road, nibi ti wọn ti n wọ mọto Ikọtun. Inu garaaji gan-an gan-an la ti wọ mọto. Eeyan meji meji lọkọ to lọ ṣaaju wa gbe. Nigba ti eleyii de, o ni eeyan mẹta mẹta loun maa gbe sori aga kọọkan.
Ẹnikan mu iṣẹ kan wa fun awakọ yẹn pe ko ba oun fun ẹnikan l’Ekoo, ẹni yẹn ni ki dẹrẹba mu nọnba foonu rẹ wa ki oun le pe e to ba ti jiṣẹ, o loun ko gba mẹseeji, o kan maa fi asiko oun ṣofo ni.
Gbogbo bi wọn ṣe n sọrọ yẹn lọwọ, mo ti n ka Kuraani. Ti emi ba ti wọkọ bẹẹ yẹn, ma a kọkọ gbe Kuraani, ma a ṣadua. nibi ti mo ti n ka Kuraani lọwọ ni mo gbọ tẹnikan beere pe dẹrẹba, ọna ibo lẹ n gbe wa lọ yii, o ni a ti fẹẹ de Toll Gate Abẹokuta.
Nigba ti mo maa gboju soke, mo ri i pe a ti wa nibi ti wọn n pe l’Aba-Odo, l’Akinyẹle. Mo ni ki la n ṣe nibi. Mo mọ ọna ibẹ yẹn nitori agbegbe yẹn lemi n gbe ni temi.
“Awakọ yẹn ni oun ko mọna ni. Bẹẹ, awakọ ero lo pera ẹ, o si ni oun ṣẹṣẹ ti Eko de laaarọ yii ni. A ni ọna eleyii ki i maa ṣe ọna Abẹokuta, bi ko ṣe mọ nnkan to maa sọ mọ niyẹn, o waa ni ka jẹ ki oun tọọnu pada. Ba a ṣe pariwo pe ko sọ wa kalẹ niyẹn.
“Nigba ti iya kan beere pe ki ni ilẹkẹ te ẹ wọ sọwọ yẹn n ṣe lọwọ yin, bo ṣe sare ja ilẹkẹ yẹn sọnu niyẹn. Ba a ṣe pariwo le e lori niyẹn ti awọn fijilante fi de ti wọn ko gbogbo wa. Awọn ọlọpaa ti mu ọkunrin yẹn naa.
“Aaye ero mẹtala lo wa ninu ọkọ yẹn. Awa ta a wa ninu mọto yẹn to ogun, nitori awọn kan gbe ara wọn lẹsẹ, emi paapaa gbe ọmọ lọwọ.
“Ọtọ ni nọmba to kọ sinu iwe. Nigba ti wọn pe nọmba to kọ sinu iwe ti awa ero kọ silẹ, ẹni to gbe e sọ pe oun wa ni Berger.
Awakọ yii ti wa lakata awọn agbofinro bayii, nibi to ti n ṣalaye ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa. SP Olugbenga Fadeyi ti i ṣe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lo fidi ẹ mulẹ bẹẹ fakọroyin wa.
Ẹ wo fidio alaye tawọn ero ọkọ ṣe: