Ọwọ tẹ Ọlayemi, ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun to n ṣoro bii agbọn l’Ogun

Adewale Adeoye

Ọjọ gbogbo ni t’ole, ọjọ kan ni t’olohun, bẹẹ gẹlẹ lo ri fun afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Ọlayẹmi Ọlawale Shedrack, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to jẹ ogbologboo ọmọ ẹgbẹ okunkun lagbegbe Ijagun, nipinlẹ Ogun. Ọwọ awọn ọlọpaa agbegbe naa ti tẹ ẹ bayii, o si ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ lahaamọ wọn.

ALAROYE gbọ pe lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa agbegbe naa ti n wa afurasi ọdaran naa lori ẹsun pe oun atawọn ẹmẹwa rẹ kan lọọ digun ja awọn akẹkọọ ileewe Tai Ṣolarin University of Education, to wa niluu Ijagun, nipinlẹ Ogun. Ile gbigbe tawọn akẹkọọ ileewe fasiti naa n gbe ti wọn n pe ni Royal Villa, ni afurasi ọdaran naa ti lọọ ṣoro bii agbọn fun wọn nibẹ, to si ji awọn ẹru olowo iyebiye lọ nibẹ. Lara awọn ẹru to ji ko ni ẹrọ kọmputa agbeletan kan, foonu igbalode, aago ọwọ ati owo. Yato si eyi, afurasi ọdaran naa atawọn ọrẹ rẹ kan tun fipa bawọn akẹkọọ ti wọn jẹ obinrin sun lọjọ naa, latigba naa si lawọn agbofinro ti n wa a ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii lagbegbe Igbẹba, nipinlẹ Ogun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, sọ pe awọn araalu kan ti wọn ri afurasi ọdaran naa lagbegbe Igbeba, ni wọn ke si awọn ọlọpaa agbegbe naa tawọn ọlọpaa si waa fọwọ ofin mu un lọ sọdọ wọn.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Igbẹba, nipinlẹ Ogun, ni afurasi ọdaran naa wa bayii, nibi to ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ lahaamọ wọn. Oun atawọn ẹmẹwaa rẹ kan ni wọn lọọ ṣoro bii agbọn fawọn akẹkọọ ileewe Fasiti Tai Ṣolarin University of Education, wọn ji dukia awọn akẹkọọ naa lọ, bakan naa ni wọn tun fipa ba wọn sun. Awọn araalu kan ti wọn da afurasi ọdaran naa mọ daadaa ni wọn pe awọn ọlọpaa teṣan Igbẹba, nigba ti wọn ri i lagbegbe wọn, o ku diẹ ko poora mọ aarin awọn ero lọjọ naa, ṣugbọn ọwọ pada tẹ ẹ.

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa patapata nipinlẹ Ogun CP Abiọdun Alamutu, paapaa ti gbọ sọrọ naa, o si ti paṣẹ pe ki wọn wọ ọ lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ki wọn le ṣewadii nipa rẹ.

Alukoro ni awọn maa ṣewadii daadaa nipa afurasi ọdaran naa tawọn si maa foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ yii, ko le fimu kata ofin fun ohun to ṣe.

Leave a Reply