Faith Adebọla, Ogun
Mẹfa lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn o jẹ kawọn eeyan adugbo Randa, iyẹn ikorita ọna to lọ si Ayetoro ati Igbo-Ọra, l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ti ko sakolo awọn agbofinro. Awọn ẹṣọ alaabo So-Safe ni wọn ṣa wọn kaakiri ibuba wọn.
Ninu atẹjade kan ti Ọga agba So-Safe, Kọmandaati Sọji Ganzallo, fi ṣọwọ s’Alaroye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, eyi ti Alukoro wọn, Moruf Yusuf, buwọ lu, wọn ni ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Emmanuel Victor, ẹni ọdun mejilelọgbọn, lọwọ kọkọ ba laarin lopin ọsẹ to kọja yii, lasiko to fẹẹ gba ẹnu geeti to wọ adugbo Fẹyintọlọrun, ni Randa, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, to loun n gbe kọja ni wọn fura si i, wọn da a duro, wọn si yẹ ara ẹ wo, wọn ba ọta ibọn ti wọn o ti i yin rẹpẹtẹ lapo ẹ, ni wọn ba mu un.
Nigba to de ọfiisi awọn So-Safe, ti wọn bẹrẹ si i ṣewadii, wọn lafurasi yii jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ loun, o niṣẹ olutọju ọgba loun n ṣe ni Fasiti Crescent, l’Abẹokuta, ibiiṣẹ loun si ti n bọ lasiko tọwọ fi tẹ oun, ti wọn si ba ọta ibọn lapo oun.
Amọ nigba ti wọn tubọ tẹ ẹ ninu, o jẹwọ pe awọn mẹfa lawọn jọ n ṣe ẹgbẹ okunkun papọ, o lawọn lawọn wa nidii ọpọ rogbodiyan to n ṣẹlẹ lagbegbe Randa, lo ba bẹrẹ si i darukọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku, bo si ṣe n darukọ wọn lo n sọ adirẹsi ile ti wọn n gbe, ati ibi ti wọn n jẹ si, loju-ẹsẹ si lawọn ẹṣọ So-Safe ti lọọ ko gbogbo wọn.
Awọn orukọ to da ni Olumide Abdullah, ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Maintain,’ o lọgaa oun ninu ẹgbẹ okunkun ni, Ojule karun-un, Opopona Adehun, n’Iyana Sẹlẹ, ni Randa lo niyẹn n gbe, o lẹni yii lo ran oun lati ba a ra ọta ibọn ti wọn ka mọ oun lọwọ, o fi kun un pe awọn ṣẹṣẹ fẹẹ ra ibọn tawọn maa maa lo ni, amọ ẹgbẹrun lọna ogun Naira tawọn tu jọ lati ra ibọn ti ba nina lọ, latari ọwọngogo owo Naira to gbode lasiko yii.
Wọn tun mu Isiaka Jimọh, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, adugbo Fẹyinlọtọrun kan naa loun n gbe, Oluwaṣeun Gabriel, ẹni ogun ọdun pere, Atunbi lorukọ inagijẹ tiẹ, Ojule kejilelogun, Opopona Opara 1, n’Iyana Sẹlẹ loun fori pamọ si, Ọjẹka Samuel, ẹni ọdun mọkandinlogun, ati Rasheed Adisa, ẹni ọdun mọkandinlogun, tawọn naa n gbe n’Iyana Sẹlẹ.
Ganzallo lawọn ọmọọṣẹ oun ti lọọ sayẹwo ile tawọn afurasi wọnyi n gbe, lara nnkan ija oloro ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni aake pelebe mẹta, ada marun-un, sisọọsi mẹrin, ọbẹ aṣooro meji, tẹsubaa tawọn Musulumi n lo meji, atawọn oogun abẹnugọngọ loriṣiiriṣii.
Atẹjade naa sọ pe wọn ti taari awọn afurasi ọdaran wọnyi si ẹka to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Oke-Ijẹmọ, l’Abẹokuta, ibẹ ni wọn maa gba de olu-ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, eyi to wa l’Eleweẹran, fun iwadii to lọọrin, ki wọn too lọ fara han niwaju adajọ laipẹ.