Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Afurasi ọmọ Yahoo kan, Franklin Akinyọsoye, lo ti wa nikaawọ ọlọpaa teṣan Fagun, to wa niluu Ondo, lẹyin ti wọn ka ori eeyan tutu mọ ọn lọwọ.
Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun lọwọ tẹ pẹlu ẹru ofin naa ninu ile to n gbe lagbegbe Elewuro, Ade Super, l’Ondo, lopin ọsẹ to kọja.
ALAROYE gbọ awọn ọmọ keekeeke kan ti wọn n ṣere jẹẹjẹ wọn ni wọn ṣe alabaapade ori ọhun ninu baagi dudu kan ti Franklin gbe e pamọ si ninu ọgba ile to n gbe.
Bi wọn ṣe foju kan an ni wọn figbe ta pẹlu ibẹru, ti wọn si sare pe akiyesi awọn agbaagba to wa nitosi si nnkan abami ti wọn ri naa.
Awọn agbaagba yii ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa Fagun leti, ki wọn too waa fi pampẹ ofin gbe ọmọkunrin ti wọn lo n ṣe Yahoo naa.
Ọkan-o-jọkan awọn ẹya ara eeyan, oogun abẹnugọngọ pẹlu ohun kan ti wọn fura si pe o ni lati jẹ ẹjẹ eeyan la gbọ pe awọn agbofinro ba ninu yara rẹ lasiko ti wọn lọọ ṣe abẹwo sibẹ.
Nigba ti wọn n fọrọ wa Franklin lẹnu wo lagọọ ọlọpaa, o jẹwọ pe oun loun ni awọn ẹru naa loootọ, o ni ọdọ babalawo kan to fi ilu Ikirun, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Ọṣun, loun ti lọọ ra wọn wa.
Ọmọkunrin yii ni wọn lo sọ sinu alaye rẹ pe oun nikan loun mọ bi awọn ẹru ajoji naa ṣe wọle sibi ti wọn ti waa ko wọn, o ni lanlọọdu oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni iṣẹ fọto yiya ati aṣọ tita ni afurasi naa sọ pe oun n ṣe.
O ni lanlọọdu rẹ lo kọkọ lọọ ko o loju lẹyin to ṣawari baagi ọhun nibi to gbe e pamọ si, to si paṣẹ fun un lati si i wo loju awọn eeyan, ki wọn le wo awọn nnkan to ko pamọ sibẹ.
O ni ori eeyan ni wọn ba lẹyin to ṣi baagi ọhun tan, leyii to mu ki wọn lọọ fi ohun to ṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti.
Ọdunlami ni afurasi ọhun jẹwọ pe babalawo kan nipinlẹ Ọṣun lo fun oun fun itẹsiwaju okoowo ti oun n ṣe.
O ni ọmọkunrin naa ṣi wa lọdọ awọn, ti awọn si n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.