Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ni gbogbo ọja teeyan maa n ta, to si maa n mowo wọle fun ni, ọmọbinrin ẹni ogun ọdun (20) kan, Agbelẹyẹ Beulah atawọn ọrẹkunrin ẹ meji, Agbekẹyẹ Ayọmide, ẹni ọdun mọkanlelogun (21), ati Ọladimeji Akintọmiwa, ẹni ogun ọdun (20), ko ri ọkankan ta nibẹ. Ọja to lodi sofin, tijọba ni ẹnikẹni ko gbọdọ mu tabi ki wọn maa ta a, iyẹn igbo, ni awọn mẹtẹẹta yan laayo lati maa ta ni tiwọn. Ṣugbọn ọwọ palaba wọn pada ṣegi, ajọ sifu difẹnsi (NCSDC) ipinlẹ Ekiti lo mu wọn, akolo wọn ni wọn si wa lasiko ta a n ko iroyin yii jọ.
Alukoro ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ naa, Ọgbẹni Tolulọpẹ Afọlabi, ṣalaye pe ọwọ tẹ Beulah atawọn yooku rẹ nibi ti wọn ti n kiri igbo atawọn egboogi oloro mi-in niluu Ado-Ekiti.
O ṣalaye pe ṣaaju akoko yii lawọn lanlọọdu adugbo Ọlọrunda, lagbegbe Adebayọ, ti kọ lẹta sileeṣẹ awọn pe awọn ọdọ kan n kiri igbo atawọn egboogi oloro mi-in lagbegbe naa.
O ni lẹyin ti awọn ri lẹta ọhun gba ni ẹka ti wọn ti n gbogun ti egboogi oloro nileeṣẹ awọn lọọ ko awọn afurasi naa nibi ti wọn ti n kiri ọja ti ko bofin mu ọhun.
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn ọdaran naa ni igbo ti wọn pọn sinu iwe pelebe, oriṣii egboogi oloro mi-in, ati ẹrọ kekere kan ti wọn fi n lẹ egboogi oloro naa lẹyin ti wọn ba pọn ọn sinu iwe tan.
O ni lasiko tawọn n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, gbogbo wọn ni wọn jẹwọ pe iṣẹ igbo ati egboogi oloro mi-in lawọn yan laayo, eyi tawọn n ta fawọn eeyan agbegbe naa.
O ṣalaye pe ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ wọn, ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.