Adewale Adeoye
Ọdọ ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro laarin ilu, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ẹka tipinlẹ Eko, ni afurasi ọdaran ọmọ orileede Canada kan, Abilekọ Adrienne Munju, ẹni ọdun mọkanlelogoji wa bayii. Ẹsun pe o fẹẹ gbe egboogi oloro kan ti wọn n pe ni Canadian loud wọ orileede Naijiria ni wọn mu un fun ni papakọ ofurufu ‘Murtala Muhammad International Airport, l’Ekoo.
ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ọwọ ajọ naa tẹ afurasi ọdaran ọhun lasiko to fẹẹ dọgbọn ko obitibiti egboogi oloro naa wọlu wa. Irin ẹsẹ rẹ ti ko mọ lo mu kawọn oṣiṣẹ ajọ naa fọwọ ofin mu un. Wọn pe e sẹgbẹẹ kan ni papakọ ofurufu naa, wọn yẹ ẹru rẹ wo finnifinni, ṣe lẹnu ya awọn to wa ni papako ofurufu naa nigba ti wọn ri egboogi oloro loud ninu ẹru rẹ. Gbogbo alaye ti wọn n bi i ni ko ri esi fi si. Kia ni wọn fọwọ ofin mu un ju sahaamọ wọn fohun to ṣe.
Alukoro ajọ naa, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, sọ pe ọkọ baalu KLM kan ni afurasi ọdaran naa wọ wa sorileede yii lati orileede Canada, nibi to n gbe.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA tẹ afurasi ọdaran kan, Abilekọ Adrienne Munju, ọmọ orileede Canada, nilẹ wa, egboogi oloro loud lo gbe wolu lati orileede Canada, ọkọ baaluu KLM lo wọ wa sorileede wa lasiko ta a fọwọ ofin mu un. A ba baagi nla mẹta lọwọ rẹ, egboogi oloro loud lo kun inu rẹ fọfọ, a fọrọ wa a lẹnu wo, ohun to sọ ni pe awọn kan lo bẹ oun niṣẹ naa, ati pe ẹgbẹrun mẹwaa dọla owo ilẹ Canada ni wọn ṣeleri lati san f’oun b’oun ba gbe ọja naa debi tawọn ran an, o ni ọda owo t’oun loun ṣe gba lati ṣiṣẹ laabi naa, ṣugbọn to pada ja si abamọ nla f’oun nigbẹyin bayii.
Alukoro ni awọn maa ṣewadii nipa afurasi ọdaran naa daadaa, tawọn si maa foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ yii, ko le fimu kata ofin.