Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti sọ pe ọwọ ti tẹ meji lara awọn ajinigbe mẹfa kan ti wọn lọọ ṣọṣẹ nileeṣẹ adiẹ kan to wa lagbegbe Atoyo, niluu Itele, nipinle Ogun.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, ni awon ikọ ajinigbe ẹlẹni mẹfa kan lọọ ji awọn oṣiṣẹ potiri ọhun gbe, ti wọn si tun pa adiẹ bii ogun lasiko ti wọn n ṣiṣẹ laabi ọhun. Ṣa o, meji lara awọn ti wọn ji gbe naa ni wọn ti gba itusile lọwọ awọn ajinigbe naa.
Ẹnikan to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti ko darukọ ara rẹ sọ pe ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ naa lawọn oniṣe ibi ọhun ya wọnu potiri ọhun, ti wọn si ba awọn eeyan marun-un nibẹ, ẹni to ni potiri ọhun paapaa wa lara awọn to ṣagbako iṣẹlẹ naa.
Loju-ẹsẹ ti wọn ti raaye wọle ni wọn ti ji gbogbo wọn gbe sa wọnu igbo kekere kan to wa lagbege naa. Wọn gba foonu ọwọ gbogbo wọn ki wọn ma baa le pe ẹnikẹni, ṣugbọn ko ju wakati bii meloo kan lẹyin ti wọn ji awọn eeyan naa ko wọnu igbo naa tan ni wọn ba ju ẹni to ni potiri ọhun silẹ ati ẹni kan ti wọn ko si jẹ ki awọn mẹta yooku bọ ninu ahaamọ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, sọ pe ẹsun ijinigbe lawọn maa fi kan awọn meji tawọn ti gba mu lori ọrọ naa, ati pe awọn ọdẹ adugbo pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ takuntakun lọwọ lati fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaran to ku ninu igbo naa laipẹ yii.
Alukoro ni awọn meji kan tawọn ọdaran naa ju silẹ ni wọn tọka si awọn tawọn fọwọ ofin mu pe wọn wa lara awọn to waa ṣọṣẹ ni potiri ọhun.
Ni ipari ọrọ rẹ, Alukoro ni laipẹ lawọn maa foju gbogbo awọn tọwọ tẹ lori iṣẹlẹ naa bale-ẹjọ, ki adajo ile-ẹjọ tawọn maa foju wọn ba le fiya to tọ jẹ wọn.