Ọwọ ti tẹ Aafaa Sala tawọn ọlọpaa n wa n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹgbẹrun saamu kan ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ loootọ, ọrọ yii lo ṣe rẹgi pẹlu bi ọwọ awọn agbofinro ṣe pada tẹ aafaa Sala Ayọdeji, ti tileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara kede gẹgẹ bii afẹmiṣofo, ti wọn si ti kede pe awọn n wa . Awọn mọlẹbi ọmọkunrin yii lo mu un, ti wọn si lọọ fa a le ọlọpaa lọwọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn ọṣu yii.

ALAROYE, gbọ pe awọn mọlẹbi Sala ti wa ọmọ wọn jade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ti wọn si lọ fa a le ọlọpaa lọwọ.

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi ọrọ naa mulẹ, o ni ọwọ ti ba Ayọdeji, tileeṣẹ ọlọpaa yoo si foju afurasi naa han si gbogbo aye laipẹ.

Tẹ o ba gbagbe lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, kede Sálà Ayọdeji, to lọọ dunkooko mọ Tajudeen ati iyawo rẹ ni ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹlifiṣan lagboole Aláràn-án, niluu Ilọrin pe awọn n wa a, wọn ni afẹmiṣofo ni.

Lara ọrọ idukooko to sọ fun wọn to da wahala naa silẹ ni pe, “To o ba mọ ẹgbẹrun eeyan, lọọ pe e, ma wa ibi mọ, tẹ ẹ ba fẹẹ ṣe mitinni, ẹ kọja si jinna rere re. Ẹyin ile Alaran, ẹ le wọn kuro nibi, ẹ sanwo wọn fun wọn o, Ọlọrun kẹ ẹ yin ju kẹ ẹ maa gba iru owo ṣọọbu bayii lọ, ẹ lewọn kuro nibi, ta a ba ba wọn nibi lọjọ mẹjọ, ko ni i rọrun o.

“Kọmisanna ọlọpaa mọ si gbogbo ohun ta a n ṣe yii, gbogbo irin-ajo yin la ti mọ, ẹ kuro nibi, ẹ maa lọ sẹyin ilu, ta a ba ba yin nibi lọjọ mẹjọ, bi awa la nilu ni, bi ẹyin lẹ nilu ni, ẹ jẹ ka jọ dan-an wo. Emi Sala Ayọdeji, lo ni a o gbọdọ ba yin nibi lọjọ mẹjọ .”

Ni bayii, ọmọkunrin naa ti wa lakata awọn ọlọpaa.

Leave a Reply