Ọwọ ti tẹ ẹ o, agbabọọlu to n gbe egboogi oloro

Monisọla Saka

Ni papakọ ofurufu Muritala Muhammed, Ikẹja, nipinlẹ Eko, lọwọ ajọ to n gbogun ti oogun oloro gbigbe ati lilo rẹ nilẹ wa (NDLEA), ti tẹ Okafor Emmanuel Junior, to ti fiogba kan jẹ agbabọọlu, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Oogun oloro kokeeni lo tọju si apa baagi to gbe lọwọ lakooko to n balẹ siluu Eko lati Sao Paulo, lorilẹ-ede Brazil, to ti n bọ. Baaluu to gba Addis Ababa, lorilẹ-ede Ethiopia, lo ba wọle.

Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Arochukwu, nipinlẹ Abia, lọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn tọwọ papaba rẹ ṣegi yii.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti NDLEA  n ṣayẹwo awọn ti wọn ba baaluu yii de ni wọn ri oogun oloro lubulubu ọhun to tọju sibi apa baagi ẹ.

Agbẹnusọ ajọ ọhun, Fẹmi Babafẹmi, ṣalaye pe, “Lasiko ta a n fọrọ wa a lẹnu wo ni Okafor jẹwọ pe oun ti figba kan jẹ agbabọọlu pẹlu ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti orilẹ-ede Naijiria to wa nipinlẹ Enugu, UNTH Enugu FC, nibi toun ti ba wọn gba bọọlu fun saa mẹrin ko too di pe oun kọja lọ sorilẹ-ede Sri Lanka, lọdun 2014.

Ilu Sri Lanka yii lo loun gba de Brazil, lẹyin toun ti gba bọọlu fun wọn fun saa meji, ṣugbọn toun o lanfaani ati tẹsiwaju ninu iṣẹ bọọlu gbigba lorilẹ-ede Brazil nitori awọn iwe igbeluu kọọkan toun ko ni”.

Adari NDLEA, Mohammed Buba Marwa, gboṣuba rabandẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ, paapaa ju lọ, awọn ti papakọ ofurufu atawọn ti eti omi nipinlẹ Eko, Abuja ati Kaduna, fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe. Bakan lo fi anfaani ọhun pe awọn to ku wọn kaakiri orilẹ-ede yii lati ji giri si iṣẹ wọn, ki wọn ma si ṣe kaaarẹ ọkan ninu iṣẹ igbogun ti awọn to n lo egboogi oloro atawọn ti wọn n gbe e sọda nibi yoowu ti wọn le fara pamọ si lorilẹ-ede yii.

 

Leave a Reply