Ọwọ ti tẹ mẹrin ninu awọn Fulani to dana sun ọkọ Amọtẹkun l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Alakooso fun ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ ni ọwọ awọn ti tẹ awọn Fulani darandaran mẹrin latari ọkada ati ọkan ninu ọkọ awọn ẹsọ aabo naa ti wọn dana sun l’Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ to kọja.

Oloye ọmọ bibi ilu Ọwọ ọhun fidi eyi mulẹ lasiko to n bawọn oniroyin kan sọrọ ni olu ileesẹ wọn to wa lagbegbe Alagbaka niluu Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ yii.

O ni ko si igba ti ẹsọ aabo Amotẹkun atawọn Fulani doju ija kọ ara wọn gẹgẹ bii ohun tawọn eeyan n sọ kiri.

Awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn n sisẹ ọtẹlẹmuyẹ fun wọn lo ni wọn ta awọn lolobo pe awọn Fulani darandaran kan sì wa ninu igbo ọba to wa nijọba ibilẹ Ọwọ lẹyin ti gbendeke ọjọ meje tijọba fun wọn ti pari.

O ni kii ṣe awọn ẹsọ ọhun nìkan ni wọn lọ, gbogbo awọn ẹsọ alaabo yooku lo ni awọn jọ kọwọọ rìn lọ sinu tawọn ọdaran naa fi ṣe ibuba lọjọ tisẹlẹ yii waye.

Bi awọn Fulani ọhun ṣe ri awọn lo ni wọn ti sare fi àwọn maluu wọn silẹ tí wọn si n salọ pẹlu ìbọn Ak47 tí wọn di mọra.

Inu igbo lo ni awọn si wa ti awọn bororo naa fi pada si abule Sanusi nitosi Ọwọ ti wọn si dana sun gbogbo ile to wa nibẹ pẹlu ọkọ ẹsọ Amọtẹkun to gbe wọn lọ la ti Akurẹ.

O ni ko sibi tí awọn ẹsọ Amọtẹkun atawọn janduku ọhun ti doju ija kọ ara wọn bẹẹ ni ko si eyikeyii ninu osisẹ awọn ti wọn yinbọn lu tabi ti wọn ji gbe.

Oloye Adelẹyẹ ni awọn afurasi mẹrẹẹrin ti ọwọ awọn pada tẹ lori iṣẹlẹ ọhun lawọn sì ń fọrọ wa lẹnu wo lọwọ.

Lẹyin ti wọn ba ti pari ifọrọwanilènuwo naa lo awọn yoo fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ fun igbesẹ to ba yẹ.

Ọpọ awọn Fulani lo ni wọn n forukọ silẹ lọdọ ijọba nigba tawọn tí ko lanfaani ati ṣe bẹẹ ti funra wọn ko ẹru wọn jade ki ọjọ ti wọn fun wọn too pe.

Ẹnikẹni ninu wọn ti ko ba ti forúkọ silẹ lo ni o gbọdọ kuro ninu igbo ọba yala wọn fẹ ni tàbí wọn kọ.

 

 

 

 

 

 

 

Leave a Reply