Ọwọ ti tẹ Sulaimon, lẹyin to ji adiẹ ko n’Ijẹbu, lo tun lọọ ji jẹnẹretọ meji gbe

Faith Adebọla, Ogun

Bi wọn ba sọ pe gende yii, Adegboyega Sulaimọn Adesanya, n rin ni bebe ẹwọn, asọdun ni o, afaimọ ni irin-ajo rẹ ọhun ko ti bẹrẹ, ko fara han niwaju adajọ lo ku, tori o ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa bayii latari ẹsun ti wọn fi kan an pe lẹyin to fo fẹnsi lọọ ja wọn lole adiẹ lọgba ti wọn ti n sin adiẹ n’Ijẹbu-Ode, ko ju ọjọ meloo kan tọwọ fi ba a nibi to ti lọọ ji ẹrọ amunawa, iyẹn jẹnẹretọ nla meji, gbe.

Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, tawọn eeyan mọ si So-Safe, ẹka ti Ijẹbu Ode, eyi ti Ọgbẹni Marcus Ayankọya n dari, awọn ni wọn mu afurasi ole yii ni nnkan bii aago marun-un aabọ idaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii, lasiko ti wọn n ṣe patiroolu kiri ilu naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro So-Safe fi ṣọwọ s’Alaroye lo ti sọ ọ di mimọ pe inu ile kan to wa ni Opopona Adelaja, nitosi Ondo Road, nijọba ibilẹ Ijẹbu-Ode, ni Sulaimọn ti lọọ ji awọn jẹneretọ meji ọhun, ọkan jẹ ẹya Okayama, ekeji si jẹ ẹya Elepaq, wọn lo n gbiyanju lati ko awọn ẹru ole ọhun sọda lafẹmọju ni wọn ka a mọ. Bi wọn si ṣe fẹẹ bi i leere ibi to ti n bọ ati ibi to n lọ, kaka ko duro lati fesi, niṣe lo ki ere mọlẹ, o fẹẹ sa lọ, amọ ere aja rẹ ko to tẹṣin ti wọn fi mu un.

Nigba ti wọn wọ ọ de ọfiisi wọn, afurasi naa jẹwọ pe loootọ loun jale, o ni niṣe loun ji awọn jẹnẹretọ naa, o loun fẹẹ lọọ ta wọn, koun si fowo ẹ ṣara rindin ni.

Wọn lafurasi yii tun jẹwọ pe oun ni ole tawọn agbofinro n wa lọjọsi, o loun loun lọọ ji adiẹ ko nile nnkan ọsin kan to wa laduugbo Idimowo, n’Ijẹbu-Ode, ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin. Wọn bi i leere pe o to adiẹ meloo to ko lọjọ naa, niṣe lo kan fesi pe o pọ, o loun o mọ iye wọn.

Ẹyin eyi lọkunrin naa bẹrẹ si i dọbalẹ pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn ma jẹ koun ṣẹwọn, ki wọn dariji oun, amọ Ọga agba So-Safe, Kọmadaati Sọji Ganzallo, ti sọ pe ọrọ ẹbẹ kọ loun to delẹ yii, o lawọn ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ lẹka ileeṣẹ wọn to wa lagbegbe Ọbalende, n’Ijẹbu-Ode, awọn si ti ko ẹsibiiti ti wọn ka mọ ọn lọwọ fun wọn pẹlu.

O ni ireti wa pe wọn yoo ṣewadii si i lori iṣẹlẹ yii, wọn yoo si foju afurasi naa bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply