Monisọla Saka
Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe adari eto iroyin fun awọn ikọ ipolongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC lasiko ibo to kọja yii, ti sọko ọrọ si olori ẹgbẹ oṣiṣẹ, Nigerian Labour Congress, (NLC), Joe Ajaero, pe ija adaja lo n ja, ko si ni i ṣe pẹlu ifẹ awọn ọmọ ẹyin rẹ.
Ninu ọrọ to kọ sori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ, ni Ọnanuga ti rọ awọn oṣiṣẹ lati ma ṣe tẹle nnkan ti Ajaero n sọ lori iyanṣẹlodi mi-in ti wọn tun fẹẹ gun le lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, nitori ọrọ owo iranwọ epo tijọba yọ.
O ni ọrọ ẹgbẹ oṣelu alatako, Labour Party, ni Ajaero n tẹle, ati pe ọna lati doju ijọba Tinubu bolẹ ni wọn n wa, ki wọn si fi han araye pe ko ri ijọba ṣe.
Ọnanuga ni, “Lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Ajaero ti pa awọn oṣiṣẹ laṣẹ pe ki wọn ma wa sibi iṣẹ mọ, nitori owo iranwọ ori epo tijọba lawọn maa yọ. Bẹẹ awọn naa mọ ọrọ gbese to wa nilẹ, eyi to mu kijọba fi fẹẹ yọwo ọhun latọjọ pipẹ. Imọran ti mo ni fawọn oṣiṣẹ atawọn ọmọ Naijiria lapapọ ni lati keti ikun sohun ti Ajaero atawọn aja ẹ n sọ. Oṣelu lo fẹẹ ti bọ ọrọ naa, ilu awọn ẹgbẹ oṣelu alatako, Labour Party, lo si n jo si lati le ba ijọba Tinubu jẹ.
“Bẹẹ, Ajaero funra ẹ mọ pe gbogbo awọn oludije funpo aarẹ lo ṣeleri lati yọwo iranwọ ori epo lasiko ti wọn n polongo. Ki waa lo de to n ṣe falafolo, abi ta lẹni to n ṣegbe fun, nigba to jẹ pe ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Peter Obi funra ẹ to n pọn si lẹyin sọ pe lọjọ toun ba depo aarẹ loun maa yọwo iranwọ ori epo rọbi”.
O tẹsiwaju pe, ijọba Tinubu ko wa lati waa ni awọn eeyan lara, ṣugbọn lati wa ọna abayọ si iṣoro to wa nilẹ. O ni ko si anfaani fun owo iranwọ ori epo mọ, nigba ti apo ijọba apapọ paapaa ti gbẹ. O ni yatọ si gbese tiriliọnu mẹtadinlọgọrin Naira (77 trillion), to wa nilẹ, ijọba apapọ tun jẹ ajọ ileeṣẹ epo rọbi ilẹ wa (NNPC), ni gbese owo iranwọ ori epo.
O sọrọ siwaju si i pe latinu oṣu Kọkanla, ọdun to kọja, lawọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ mejeeji, NLC ati TUC, ti mọ pe ọjọ kin-in-ni, oṣu Keje, ọdun yii, ni wọn yoo ṣiwọ sisan owo iranwọ, nitori bi ko ṣe si ninu eto iṣuna ọdun 2023 yii, ati pe, ko le kọja oṣu Kẹfa yii, ti wọn yoo fi yọpa yọ ẹsẹ wọn ninu sisanwo naa.
O ni, “Ida mẹrindinlọgọrun-un, ninu owo to n wọle si apo ijọba apapọ ni wọn ti ya sọtọ bayii fun gbese sisan, wọn ko si ni i le tẹsiwaju pẹlu owo iranwọ mọ. Epo ti ki i ṣe ojulowo naa kuku ni wọn fi n ta, ti wọn n fi iwa ọdaran gbe e gba ẹnu ibode awọn ilu kaakiri lọna ti ko bofin mu, ti ko si mu èrè wọle taratara.
‘‘Mo wa n fi asiko yii rọ awọn ọmọ Naijiria atawọn oṣiṣẹ, lati gbaruku ti ijọba pẹlu bi wọn ṣe n ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe agbekalẹ owo oṣiṣẹ to kere ju lọ mi-in, atawọn ọna mi-in ti wọn le gba ran wọn lọwọ. Aarẹ ti ṣeleri yii tẹlẹ, lati le mu aye rọrun fawọn eeyan, latari inira yoowu ti iye owo jala epo ti wọn ṣẹṣẹ ṣagbekalẹ rẹ le fẹẹ da silẹ”.
O ni Ajaero ti kuro ni ọga awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ, oloṣelu ni bayii, ọmọ ẹgbẹ Labour Party si ni, nitori ko ṣoju fawọn oṣiṣẹ mọ, ọrọ to n dun un lo fi n ṣe ija ja.
O kilọ fawọn eeyan lati ma ṣe jọwọ ara wọn silẹ fẹni to n ja fun ifẹ-inu ati apo ara rẹ nikan.