Faith Adebọla
Lojuna ati wa ojutuu si wahala owongogo owo Naira tuntun to gbode kan lasiko yii, ipade pataki kan ti waye laarin awọn gomina ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ati Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Mohammadu Buhari.
Gbọngan apero ti wọn n pe ni Council Chambers, eyi to wa lọfiisi Aarẹ, l’Abuja, nipade naa ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Keji ta a wa yii.
Awọn gomina APC ti wọn n pe ara wọn ni Progressives Governors’ Forum (PGF) ni wọn kora jọ lati ba aarẹ fikun lukun lori awọn ọrọ pataki kan.
Bo tilẹ jẹ pe wọn o ṣiṣọ loju eegun ohun tipade naa da le, Alaroye gbọ pe ọpọ awuyewuye to n lọ nigboro, lagbo oṣelu ati lori ẹrọ ayelujara, bii ọrọ nipa owo tuntun to wọn bii imi eegun, ọwọngogo epo bẹntiroolu to n peleke si i, ẹsun ti gomina ipinlẹ Kaduna fi kan ileeṣẹ Aarẹ pe awọn aworoṣaṣa kan n fi ori mulẹ ti wọn n gbẹyin bẹbọ jẹ fun eto ipolongo ibo oludije funpo aarẹ wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati lọgbọ-lọgbọ abẹnu to n lọ laarin awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC, wa lara awọn ọrọ gboogi ti wọn fẹẹ sọ nipade ọhun.
Gomina ipinlẹ Kebbi, Atiku Bagudu, to jẹ alaga awọn gomiona PGF yii lo ṣaaju awọn gomina ọhun.
Lara awọn gomina to wa sibi ipade naa ni Dave Umahi ti ipinlẹ Ebonyi; Babajide Sanwo-Olu lati Eko; Hope Uzodimma ti Imo; Bello Matawale tipinlẹ Zamfara; Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun; Mai Bala-Buni lati Yobe; Nasir El-Rufai ti Kaduna; Abdullahi Ganduje tipinlẹ Kano; Abdul Rahman Abdulrazak, gomina ipinlẹ Kwara) ati Sani Bello gomina ipinlẹ Niger ati awọn mi-in.
Awọn gomina naa ti parọwa si Aarẹ Buhari pe ko yọnda, ko si faṣẹ si i kawọn araalu maa na owo atijọ ati owo tuntun naa lọ tayọ gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ti wọn ni owo atijọ naa ko ni i ṣee na mọ, wọn eleyii yoo din inira ati aroye to n lọ nigboro lori airowo tuntun na ku.
Gomina El-Rufai, to fede Hausa ba awọn oniroyin sọrọ ṣoki sọ pe awọn ti jẹ ki Buhari mọ ipenija ti owo tuntun naa n lori ọrọ-aje, okoowo ati kara-kata awọn araalu. O ni loootọ ni banki apapọ ilẹ wa lawọn ti ri owo atijọ ti iye rẹ to tiriliọnu meji Naira ko kuro nilẹ, amọ iye owo tuntun ti wọn tẹ jade ko ju ọọdunrun miliọnu Naira (N300 milliion) lọ, eyi ko si le debi kan, tori ko too na fawọn eeyan.
Gomina Kaduna ni gbogbo alaye yii lawọn ti ṣe fun Buhari, amọ Aarẹ ko ti i fawọn lesi pato kan, boya yoo gba arọwa awọn o, abi ko ni i gba a wọle