Florence Babaṣọla, Oṣogbo
O kere tan, ibo miliọnu kan ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, fọwọ ẹ sọya pe o ti wa nilẹ nipinlẹ Ọṣun fun oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.
Oyetọla sọrọ yii ni ọfiisi ipolongo ibo rẹ niluu Oṣogbo, lasiko to n gba ogunlọgọ awọn ọdọ ti wọn rin kaakiri ilu Oṣogbo lati fi atilẹyin wọn han fun erongba Tinubu/Shettima lalejo.
Awọn ọdọ naa ni wọn ko wo ti ojo to n rọ, ti wọn lọ kaakiri awọn ibi to ṣe koko niluu Oṣogbo lati sọ fun awọn araalu pe ti wọn ba dibo wọn fun Tinubu lọdun 2023, idagbasoke ti ko lẹgbẹ ni yoo ba orileede Naijiria.
Oyetọla, ẹni to fi ijọloju rẹ han fun bi awọn ọdọ naa ṣe tu yaaya jade lai ti i to asiko idibo, fi da wọn loju pe iṣejọba Tinubu/Shettima yoo jẹ eyi ti yoo ko awọn ọdọ orileede yii mọra.
O ni pẹlu igbesẹ ti awọn ọdọ naa gbe, o fi han pe gbọingbọin ni ẹgbẹ oṣelu APC wa nipinlẹ Ọṣun lai foya rara.
O ni afojusun Tinubu ni lati sin awọn eeyan orileede Naijiria, lati mu itẹsiwaju ba awọn araalu ni gbogbo ẹka bii eto-ẹkọ, eto ilera, iṣẹ agbẹ, eto ọrọ-aje ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oyetọla ni oun nidaaniloju pe ibo to le ni miliọnu kan ni ẹgbẹ oṣelu APC yoo fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Shettima, ninu idibo apapọ ọdun 2023.
Ṣaaju ni alakooso awọn ọdọ naa, Goke Akinwẹmimọ, ti fi da gomina loju pe didun lọsan yoo so fẹgbẹ naa lọdun 2023, o si rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati dibo wọn fun Tinubu/Shettima.