Oyetọla/Adeleke: Furaidee, ọsẹ yii, nile-ẹjọ Kotẹmilọrun yoo gbe idajọ kalẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lọwọlọwọ bayii, ko si eyi ti ọkan rẹ balẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP nipinlẹ Ọṣun, pẹlu bi ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ṣe ti ṣetan lati gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ibo gomina to waye lọdun to kọja.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn adajọ ẹlẹni mẹta naa, eleyii ti Onidaajọ Mohammed Shuaibu jẹ alaga fun, gbọ awijare awọn agbẹjọro olujẹjọ ati olupẹjọ.

Ikede to wa lati ile-ẹjọ yii to fikalẹ si Abuja fihan pe aago mejila ni awọn adajọ naa yoo ka idajọ wọn.

Oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni igbimọ ẹlẹni-mẹta to kọkọ gbọ ẹsun naa niluu Oṣogbo, labẹ alaga wọn, Onidajọ Kume, gbe idajọ kalẹ, meji lara awọn onidaajọ naa gba pe adiju ibo waye lawọn ibudo idibo kọọkan.

Nigba ti wọn yọ awọn ibo naa kuro ninu ojulowo ibo ti ajọ INEC fi kede Adeleke gẹgẹ bii gomina ni wọn ri i pe ibo Oyetọla ju ti Adeleke lọ, nitori naa, wọn ni ki ajọ INEC gba satifikeeti ọwọ Adeleke, ki wọn si fun Oyetọla.

Ṣugbọn Gomina Adeleke, ẹgbẹ oṣelu PDP ati ajọ INEC fori le ile-ẹjọ Kotẹmilọrun, wọn ni idajọ naa ni ọwọ kan eru ninu, ati pe adajọ ko lẹtọọ lati yọ ibo adiju kuro ninu esi ibo.

Nile-ẹjọ Kotẹmilọrun ni agbẹjọro Adeleke, Onyechi Ikpeazu ati ti Oyetọla, Lateef Fagbemi, ti ro arojare wọn, lẹyin naa si ni Onidaajọ Shuaibu sọ pe awọn yoo fi ọjọ idajọ ṣọwọ si wọn laipẹ.

Ọjọ idajọ naa lo si ti de yii. Ni bayii, oju gbogbo lo wa lara ile-ẹjọ Kotẹmilọrun naa, abala mejeeji lo si n leri kaakiri pe didun lọsan yoo so fawọn.

Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun awuyewuye to suyọ ninu eto idibo l’Ondo ti gba iwe ipẹjọ mẹwaa

 

Leave a Reply