Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbọnmọ-gbọnmọ nijọba ipinlẹ Ọṣun n lọgun rẹ bayii pe ko gbọdọ si ipejọpọ kankan fun isin aisun ọdun to yẹ ko waye lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to n bọ yii.
Atẹjade kan ti Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, fi sita nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lo ti ke si awọn agbofinro lati ṣan ṣokoto wọn giri, ki wọn si fi panpẹ ofin gbe awọn to ba pe jọ pọ lati ṣe isin naa.
Oyebamiji ṣalaye pe ọwọ yẹpẹrẹ lọpọlọpọ ṣi fi mu ọrọ ajakalẹ arun Koronafairọọsi, ijọba ko si gbọdọ fọwọ lẹran woran.
Oyebamiji ni bii ina inu ẹẹrun ni arun naa n ran kaakiri bayii, gbogbo ilana idena rẹ si lo pọn dandan bayii pe ki awọn araalu maa tẹlẹ.
O ni awọn agbofinro yoo maa lọ kaakiri lati ri i pe ko si isin aisun ọdun (Cross over nights) nibikibi nipinlẹ Ọṣun, nitori ojuṣe ijọba ni lati pese aabo fun ẹmi awọn araalu.
Akọwe ijọba yii ni ko si aaye akunfaya nileejọsin; yala ṣọọṣi tabi mọṣalaasi, bẹẹ ni fifọwọ pẹlu omi to mọ ati lilo oogun apakokoro ṣe pataki, ojuṣe gbogbo eeyan si ni lati le Korona jinna nipinlẹ Ọṣun.