Jide Kazeem
Nitori bi awọn eeyan ṣe tẹle ofin konilegbele oni wakati mẹrinlelogun ti gomina Ọṣun, Isiaka Oyetọla paṣẹ rẹ, ijọba ti sọ pe awọn ti fagi le konilegbele nipinlẹ naa, wọn ni awọn araalu le maa jade sita.
Oyetọla dupe lọwọ awọn araalu fun ifarada ati agbọye ti won ni pẹlu ijọba, bẹẹ lo gboriyin fun awọn ọdọ pẹlu bi wọn ṣe ṣe iwọde naa lọna ti ko mu wahala kankan dani.
Gomina ni. ‘‘Lẹyin ti a ti ṣe agbeyẹwo bi awọn eeyan ṣe tẹle ofin konilegbele naa, ta a si tun ti gbe igbimọ oluwadii ti yoo ri si ifiyajẹni awọn SARS dide, a ti wọgi le ofin konilegbegbe to ti wa niluu telẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
‘‘A gbe igbesẹ yii lati fun awọn araalu ni anfaani lati lọ sibi ijokoo igbimọ ta a ti ṣagbekalẹ rẹ yii, ati lati fun awọn araaalu lanfaani lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ.
‘‘Ijọba ko ni i fọwọ jẹpẹrẹ mu ọrọ awọn ọdọ, bẹẹ ni gbogbo igbesẹ to yẹ la maa gbe lati ri i pe a dahun si awọn ohun ti wọn n beere fun.
‘‘Niwọn bi ijọba ti ṣetan lati ṣe ohun ti awọn ọdọ n fẹ, A rọ awọn ọdọ lati dawọ ifẹhonu han duro, ki wọn si ni asọyepọ pẹlu ijọba.
‘‘A waa rọ gbogbo awọn araalu lati ṣe jẹẹjẹ, ki wọn gba alaafia laaye, ki wọn si ma ṣe huwa ti yoo da alaafia ilu ru, gẹgẹ bi awa naa ṣe n sapa lati ri i pe aabo wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu.
‘‘Ki Ọlọrun bukun ipinlẹ Ọṣun.’’ Gomina Oyetọla lo sọ bẹẹ.