Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti sọ pe ohun pataki meji ni Ọlọrun ba oun sọ nipa ọdun 2023, oun si nigbagbọ pe mejeeji ni yoo wa si imuṣẹ.
Ohun akọkọ, gẹgẹ bo ṣe sọ, ni pe oun yoo gba ipo oun pada gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun yii, ati pe erongba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati di aarẹ orileede yii yoo wa si imuṣẹ.
Nibi eto adura kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọṣun ṣe lati fi bẹrẹ ọdun tuntun ni Oyetọla ti sọrọ idaniloju naa. O ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ APC mu ọkan le, ki wọn ma ṣe faaye gba irẹwẹsi rara nitori dandan ni ki ileri Oluwa ṣẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni isinmi ranpẹ loun lọ fun, yatọ si pe oun ni aaye lati ba awọn ẹbi oun ṣere daadaa, oun atiyawo oun tun lọ waa oju Ọlọrun ni Umurah.
O ni inu oun dun lati pada wale, iyalẹnu lo si jẹ fun oun bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe tu yaaya jade lati pade oun lai sọ fun wọn tẹlẹ pe oun n bọ.
Oyetọla waa fi aidunnu rẹ han si bo ṣe jẹ pe kaadi idibo bii miliọnu kan lo wa lọdọ ajọ INEC Ọṣun ti wọn ko ti i gba, o rọ awọn araalu lati tete lọọ gba kaadi naa lati le fi di ibo wọn fun awọn oludije ninu ẹgbẹ APC ninu idibo apapọ ọdun yii.
Ṣugbọn nigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP n fun Oyetọla lesi ọrọ, ẹgbẹ naa ni ki i ṣe Ọlọrun lo n ba a sọrọ, eṣu lo n rojọ si i leti nitori ipinlẹ Ọṣun ti sun siwaju.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun Gomina Adeleke, Mallam Rasheed Ọlawale, fi sita lo ti ṣalaye pe ki Oyetọla tete lọ gbagbe erongba pe oun yoo pada sipo gomina l’Ọṣun nitori Ọlọrun gan-an fẹran idajọ ododo.
Ọlawale ni ṣe lo yẹ ki Oyetọla lọọ maa ka “auzubilahi mina shaytani rajeem’ ko baa le gbọ ohun (voice) Ọlọrun kedere, ko si le tete gba kamu pe ejo ti wọ kuro nibi ana nipinlẹ Ọṣun.
Tẹ o ba gbagbe, gomina naa ti pe ẹjọ ta ko bi Gomina Adeleke ṣe jawe olubori ninu eto idibo naa, eyi ti igbẹjọ rẹ si n lọ lọwọ.