Ofin ka maa fi maaluu jẹko ni gbangba kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ-o-sọka nipinlẹ naa. Gomina wọn, Adegboyega Oyetọla, lo buwọ lu abadofin naa, to sọ ọ dofin.
Ṣaaju lawọn aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti pari iṣẹ lori abadofin ọhun, eyi ti wọn ti n jiroro lori rẹ lati ọsẹ meloo kan sẹyin, bi wọn ti pari iṣẹ lori abadofin ọhun, ti wọn si lu u lontẹ, ni wọn taari ẹda kan si gomina wọn lati buwọ lu u.
Akọwe Iroyin fun gomina, Ọgbẹni Ismaila Omipidan, lo fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, o ni Gomina Oyetọla ti faṣẹ si abadofin naa, o ti buwọ lu u, o si ti sọ ọ di ofin ti wọn yoo ṣamulo rẹ nipinlẹ wọn.
“Gomina ti buwọ lu ofin to ta ko fifi ẹran jẹko ni gbangba nipinlẹ Ọṣun lẹsẹkẹsẹ ti abadofin naa dori tabili rẹ latọdọ awọn aṣofin ipinlẹ wa.
A ti ba awọn agbofinro ati ẹṣọ alaabo gbogbo sọrọ lori ofin yii, wọn gbọdọ ri i pe ofin naa di mimuṣẹ kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọṣun.
‘‘Ọkan ninu awọn ipinlẹ ti alaafia ti jọba lorileede yii nipinlẹ wa, a o si fẹẹ ni wahala awọn darandaran to n ba oko oloko jẹ tabi ti wọn n ṣe akọlu sawọn agbẹ nibi, tori igbimọ kan ta a gbe kalẹ lati ri si igbe alaafia laarin awọn agbẹ ati awọn Fulani ati Bororo n ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ gidi ni, Ọnarebu Mudaṣiru Toogun lo ṣalaga igbimọ naa.
‘‘Ka too ṣofin yii, a ti sọ asọye pọ pẹlu awọn tọrọ kan lati jiroro daadaa lori ọrọ yii, a si ti la awọn darandaran lọyẹ nipa anfaani to wa ninu fifẹranjẹko lọna ti igbalode. A ti ṣalaye pe ki wọn kan si ẹka to n ri si iṣẹ ọgbin nipinlẹ yii fun itọsọna bi wọn ṣe le ṣe e.”
O ṣalaye pe ofin tuntun yii maa ṣiṣẹ lati daabo bo awọn araalu lọwọ ipakupa, ifipabanilopọ, ihalẹmọni, biba ire oko jẹ ati biba ayika jẹ pẹlu.
Ninu ofin naa, ọmọ ti ko i tojuubọ to ba n da maaluu kiri ṣẹ lodi si isọri kẹta ati ikẹrin, awọn obi ati alagbatọ iru ọmọ bẹẹ maa sanwo itanran ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, afi to ba jẹ pe wọn n tẹle majeṣin to n da maaluu ọhun kiri.
Bakan naa, eewọ ni lati maa da maaluu kiri lori ilẹ, lati ibi kan si omi-in, koda teeyan ba fẹẹ fi mọto tabi reluwee ko iru ẹran bẹẹ paapaa, o gbọdọ jẹ laarin aago meje alẹ si aago mẹfa owurọ, aijẹ bẹẹ, tọhun yoo lufin ọba.