Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ti sọ pẹlu idaniloju pe Alhaji Gboyega Oyetọla yoo pada gẹgẹ bii gomina ko too di ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun ti a wa yii.
Lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ igbimọ ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ APC ni ọfiisi Tinubu/Shetimma to wa niluu Oṣogbo, ni Owoẹyẹ fi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lọkan balẹ pe didun lọsan yoo so fun wọn nitori laipẹ ni Oyetọla yoo gba ẹtọ rẹ pada.
O ran wọn leti pe ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun 2019, ni ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii kede Oyetọla gẹgẹ bii oludije to jawe olubori ninu ibo oṣu Kẹsan-an, ọdun 2018, o ni ọjọ yii kan naa nile-ẹjọ to ga ju lọ yii yoo tun gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ to n lọ lọwọ laarin Adeleke ati Oyetọla.
O ni “Ṣe ni wọn ro pe awọn le ṣe eru, ọpẹlọpẹ ẹrọ BIVAS to tu wọn laṣiiri. Mo fi n da yin loju pe Gomina Oyetọla yoo gba ẹtọ rẹ pada ninu oṣu Keje, ọdun yii.”
Owoẹyẹ fi kun ọrọ rẹ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe awọn aṣofin kan ti n gbero lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, o ni gbọn-in-gbọn-in lawọn wa ninu ẹgbẹ Onitẹsiwa, APC.
Ninu ọrọ rẹ, Oyetọla ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ gidigidi fun aṣeyọri Aṣiwaju Bọla Tinubu ati igbakeji rẹ, Shetimma.
O ni ohun to daju gbangba ni pe ibo to le ni miliọnu kan ni Tinubu yoo ri nipinlẹ Ọṣun ninu idibo aarẹ ti yoo waye loṣu Keji, ọdun yii.
Oyetọla ke si gbogbo awọn ti wọn ko ti i gba kaadi idibo wọn lati tete ṣe bẹẹ nitori agbara kan ṣoṣo ti wọn ni lati dibo fun oludije to ni ifẹ awọn eeyan orileede Naijiria lọkan niyẹn.
O ni oniruuru iṣẹ idagbasoke ni Tinubu ṣe lasiko to fi jẹ gomina ipinle Eko, ipa rẹ ko si ṣee fọwọ rọ sẹyin titi doni, gbogbo awọn ọgbọn atinuda naa ni yoo si lo lati fi tun orileede Naijiria ṣe to ba di aarẹ.