Oyinbo Chinese meji ti dero ẹwọn ni Kwara, eyi lohun ti wọn ṣe 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ kan to filu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ṣe ibujokoo, ti sọ oyinbo Chinese meji kan, Duan Ya Hong ati Xiao Yi, ṣẹwọn ọdun kọọkan. Ẹsun wiwa kusa lọna aitọ ni wọn fi kan wọn.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, (EFCC), ẹka tipinlẹ Kwara, lo wọ awọn oyinbo Chinese mejeeji ọhun lọ siwaju ile-ẹjọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, fẹsun pe wọn n lọọ wa kusa niluu Bánní, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara, lai gba aṣẹ lọjọ ijọba, tọwọ si tẹ wọn ninu oṣu Keji, ọdun 2024 yii.

Aṣoju EFCC, Innocent Mbachie, ṣọ fun ile-ẹjọ pe, “Iwọ, Ebuy Trading Worldwide Nig. LTD, Duan Ya Hong, Xiao Yi, nigba kan ninu oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lọ si ilu Bánní, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara, lati lọọ ko ohun alumọọni kan bii ọgbọn paali, ti ẹ si fi ọkọ tirela kan to ni nọmba JJJ 386 XT ko o lai gba aṣẹ lọwọ ijọba, leyii to ta ko iwe ofin ilẹ wa, ti ijiya rẹ si wa ni abala kin-in-ni, ninu iwe ofin ilẹ wa tọdun 1984, fẹni to ba ṣe bẹẹ”. Innocent ko awọn ẹri maa jẹ mi niṣo siwaju adajọ.

Lẹyin atotonu igun kin-in-ni ati ikeji ni Onidaajọ Evelyn Anyadike, gbe idajọ rẹ kalẹ pe awọn oyinbo mejeeji jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, fun idi eyi, ki Hong, lọọ fi ẹwọn ọdun kan jura pẹlu iṣẹ aṣekara tabi ko san miliọnu meji Naira gẹgẹ bii owo itanran.

Bakan naa lo ni ki Yi, naa lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun ọdun kan gbako, tabi ko san owo itanran miliọnu kan aabọ Naira gẹgẹ bii owo itanran. Bẹẹ ladajọ tun paṣẹ pe ki gbogbo dukia ti wọn ba lọwọ wọn di ti ijọba apapọ fun igba diẹ.

 

Leave a Reply