Ọyọmesi din orukọ awọn to n dupo Alaafin ku si mẹwaa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọyọmesi, iyẹn awọn afọbajẹ ilu Ọyọ ti din orukọ awọn to n dupo Alaafin ku si mẹwaa.

Eyi ko ṣẹyin bi mẹrindinlọgọrin (76) ninu awọn to n dupo ọba naa ṣe fidi-rẹmi ninu ayẹwo ti awọn afọbajẹ ti n ṣe fun wọn lati ọsẹ meji sẹyin, eyi to wa sopin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Baṣọrun Ọyọ, Agba-Oye Yusuf Akinade Ayọọla (Ọlayinka Kin-in-ni), to tun jẹ Adele Alaafin lọwọlọwọ bayii, lo fidi iroyin yii mulẹ.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Bọde Durojaiye ti i ṣe alamoojuto eto iroyin fun Alaafin Ọyọ fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, Agba-Oye Ayọọla sọ pe “A ti pari ayẹwo fawọn ọmọ oye to n dupo Alaafin. Marundinlaaadọrun (65), ninu awọn mẹrindinlaaadọrun (86), ni wọn fara han fun ayẹwo naa.

“Ni bayii to jẹ pe eeyan mẹwaa lo kunju oṣunwọn ninu awọn ọmọ oye, igbesẹ to kan bayii ni lati difa, lati yan ọkan ṣoṣo to maa jẹ Alaafin ninu awọn mẹwẹẹwa.

“Gbogbo ayẹwo ta a ṣe ọhun ko ṣẹyin ijọba, alaga ijọba ibilẹ Atiba lo ṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ ninu eto ayẹwo maa. Ijọba ipinlẹ Ọyọ naa la si maa pada fi orukọ ẹni ti Ifa ba yan gẹgẹ bii Alaafin tuntun ranṣẹ si”.

 

Nigba to n tako ahesọ iroyin to n ja rainrain kiri pe ẹgbẹrun lọna igba Naira (₦200,000) lawọn Ọyọmesi gba lọwọ ọmọ oye kọọkan lasiko ayẹwo, Agba-Oye Ayọọla rọ awọn to n gbe iru iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ kiri lati jawọ nibẹ nitori iru iroyin ibajẹ bẹẹ ko ni anfaani kankan ninu.

 

Leave a Reply