Oyun ibeji lo wa nikun ọmọ mi tọlọpaa yinbọn pa -Iya Ọmọbọlanle

Faith Adebọla 

“Mi o ni i ri lọọya mi mọ, wọn ti gba a lọwọ mi o, haa, wọn ti gba a lọwọ mi. Oyun ibeji lo wa nikun ẹ, wọn pa a togo-togo, o fọmọ ọdun marun-un silẹ fun mi.

“Ọmọ ti mo ti n wo, ti mo ti n re bọ lati kekere, mo ṣiṣẹ, mo jiya lori ẹ. Mo kiri ọsan danwo, ko si nnkan ti mi o ṣe titi tọmọ mi fi di lọọya. Asiko to waa jẹ idunnu fun mi… Iwọ Ọlọrun o, ja fun mi o. Mo ti fi i silẹ f’Ọlọrun o, Ọlọrun aa ja fun mi. Ọmọ kan ṣoṣo to ku mi ku ni wọn pa danu yii, ṣugbọn mo ti gbọ o, mo ti fi i ṣilẹ f’Ọlọrun o.”

Eyi ni diẹ ninu awọn ọrọ ẹdun ọkan ati idaro, ti Abilekọ Salami ti i ṣe iya Oloogbe Ọmọbọlanle Raheem, ti ọlọpaa yinbọn pa nipa ika lọjọ ọdun Keresi, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila yii, labẹ biriiji Ajah, l’Erukuṣu Eko, sọ lasiko ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Abiọdun Alabi, atawọn ẹmẹwa rẹ ṣabẹwo ibanikẹdun sawọn mọlẹbi oloogbe naa.

Lai ka bi wọn ti n rẹ mama agbalagba naa lẹkun to, niṣe lo n sun ẹkun asunwa, ọgbẹ ọkan gidi si niṣẹlẹ naa jẹ fawọn mọlẹbi ọhun. Niṣe ni gbogbo agboole wọn kan gbinrin-gbinrin, atonile atalejo to si wa nibẹ loju wọn kọrẹ lọwọ.

Iya Ọmọbọlanle tun sọ pe: “Lọjọ Mọnde, iyẹn ọjọ keji iṣẹlẹ yii, ọmọọmọ mi waa ba mi nibi ti mo ti n sunkun, o ni ‘Grandma Iju Iṣaga, mo ri yin lanaa tẹ ẹ n sunkun, ẹ ma sunkun mọ, ṣe nitori mọmi mi ni? Pasitọ Jerry ti ni ko sohun t’Ọlọrun ko le ṣe. Mama agba, ẹ yee sunkun,” lo ba bẹrẹ si i fọwọ nu omije nu loju mi.

“Ṣe wọn ti gba ọmọ mi lọ mọ mi lọwọ naa niyẹn. Haa, (o kọju si ọkọ ọmọ ẹ) Oluwagbenga, o o ri ifẹ ẹ mọ. O ma ṣe o, ina ọmọ ma jo mi o, ina buruku leyi o.”

Titi dasiko yii lọkan-o-jọkan ọrọ idaro n rọjọ lori iṣẹlẹ aburu ọjọ Keresi ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ naa ni ọkan ninu awọn ọlọpaa ti wọn wa to n ṣiṣẹ ni teṣan Ajiwe, l’Ajah, lagbegbe Lẹkki, ASP Drambi Vandi, fibọn da ẹmi agbẹjọro ẹni ọdun mọkanlelogoji naa, Abilekọ Ọmọbọlanle Raheeem, legbodo, toyun-toyun, ti iku gbigbona yii si ti fopin si ireti obinrin arẹwa ọhun lati bimọ le ọmọ kan ṣoṣo to ni.

Leave a Reply