Pasitọ Tunde Bakare ranṣẹ ikilọ nla si Tinubu

Faith Adebọla

Oludasilẹ ijọ Latter Rain, ti wọn n pe ni Citadel Global Community Church bayii, Pasitọ Tunde Bakare, ti parọwa si Olori orileede wa, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, pe ki i ṣe awọn ọmọ Naijiria lo yẹ ko doju ogun kọ lasiko yii, pẹlu bi inira ati ipọnju ṣe n ba awọn araalu finra, o ni iwa ajẹbanu lo yẹ ki Aarẹ yọ kumọ ti, ko si lu u pa, ki i ṣe awọn ti wọn dibo fun un.

Ọrọ yii lo wa ninu iwaasu pataki kan ti Oluṣọ-aguntan agba ni ṣọọṣi Citadel ọhun ka jade fawọn ọmọ ijọ rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ yii, ni ṣọọṣi rẹ to wa lọna Kudirat Abiọla Way, Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Nisọri-isọri ni Bakare sọ awọn ọrọ rẹ ọhun. Nigba to n sọrọ lori awuyewuye to n lọ lọwọ nipa igbesẹ ti ajọ ECOWAS ti Tinubu jẹ alaga rẹ fẹẹ gbe lati lọọ doju ogun kọ awọn ṣọja to gbajọba lorileede Niger, Bakare, toun ati Tinubu jọọ dije funpo aarẹ lasiko eto idibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lọdun to kọja, sọ pe: “Ko sigba kan tawọn eeyan orileede Niger fi tara-tara gba ti Naijiria. Nitori eyi, ọrọ to le bẹyin yọ ni bi a baa lọọ kogun ja wọn. Loootọ, ko daa bi iditẹ-gbajọba ṣe n waye lawọn orileede Iwọ-Oorun ilẹ Afrika kọọkan, a o si fara mọ ọn, ṣugbọn a gbọdọ mọ pe ọrọ to de’lẹ yii gba kawọn olori orileede nilẹ Afrika ronu jinlẹ, ki wọn ronu siwa sẹyin nipa iṣejọba rere.”

Lori inira tawọn araalu n koju latigba tijọba ti yọwọ kilanko wọn lori owo iranwọ ori epo bẹntiroolu, Pasitọ Bakare ni: “Aarẹ, inira yii ti pọ ju, iwa ajẹbanu ni kẹ ẹ yọ kumọ ti, kẹ ẹ lu u pa, ki i ṣe awọn ọmọ Naijiria. Ko si eto ọrọ-aje to le seeso rere kan nigba tawọn alaṣẹ ba n jaye alabata.”

O tun fikun un pe: “A ke sawọn alaṣẹ Naijiria bayii lati jẹ olori rere. Ṣugbọn ibeere naa ni boya Aarẹ Tinubu ni agbara ati ohun amuyẹ lati jẹ iru olori bẹẹ, ka tiẹ kọkọ bẹrẹ labẹle wa na.”

Bakan naa ni Bakare kede pe lati asiko yii lọ, Ọlọrun sọ foun pe Oun maa da si ọrọ orileede yii. O ni “Lẹyin ikede ti mo n ṣe yii, ẹ maa ri i pe Ọlọrun maa ṣiṣẹ lori orileede yii. Ẹ kọ ọjọ oni silẹ, kẹ ẹ si sami sakoko yii, Ọlọrun maa da si ọrọ orileede Naijiria yii ni ti gidi. A gbọdọ sọ ohun ti Oluwa sọ fun wa, to si fi han wa, fun yin.”

Leave a Reply