Monisọla Saka
O da bii pe ọrọ ti iwe mimọ sọ pe bi opin aye ba ti n sun mọ, oriṣiiriṣii awọn nnkan ti ko ṣẹlẹ ri ni yoo maa ṣẹlẹ, lo ṣẹ mọ Pasitọ kan, Makenzie Nthenge, ijọ Good News International Church, lorileede Kenya, lara. Niṣe ni ọkunrin to pe ara ẹ niranṣẹ Ọlọrun yii paṣẹ fun awọn ọmọ ijọ rẹ pe ki wọn ma jẹ, ki wọn ma si mu fun ọpọlọpọ ọjọ, o ni ti wọn ba ṣe bẹẹ, wọn yoo ri Jesu.
Imọran yii ni pupọ ninu awọn ọmọ ijọ naa tẹle ti ebi fi pa mẹrin ku ninu wọn, ti ọpọ si wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun lọsibitu, nibi ti wọn ti n gba itọju, gẹgẹ bi Ileeṣẹ iroyin ilẹ Kenya kan ṣe sọ.
Awọn eeyan agbegbe kan ti wọn n pe ni igbo Shakahola, nitosi ilu kan to n jẹ Malindi, ni wọn ta awọn agbofinro lolobo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, pe awọn eeyan kan ti sọda sọrun latari ebi, lẹyin ti pasitọ ijọ ti wọn n lọ kógbó si wọn lori pe wọn yoo pade Jesu ti wọn ba febi pa’nu, ti wọn ko jẹun fun ọpọlọpọ ọjọ.
Nigba tawọn agbofinro yoo fi debẹ, mẹrin ninu awọn ọmọ ijọ yii ti dagbere faye. Ni wọn ba sare gbe awọn mọkanla yooku digbadigba lọ sileewosan. Mẹta ninu awọn ti wọn wa l’ọsibitu ni wọn wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun, ti ko sẹni to le sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si wọn pẹlu ipo to lagbara ti wọn wa.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin meje, obinrin mẹrin, tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹtadinlogun (17), si mọkandinlaaadọta (49), lawọn mọkanla ti wọn wa nileewosan yii.
Gẹgẹ bi olori ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran lagbegbe Malindi, Charles Kamau, ṣe sọ, o ni, “A ti fi panpẹ ofin gbe pasitọ yẹn lẹyin to jọwọ ara rẹ silẹ fun wa, nitori o mọ pe a n wa oun”.
Kamau ni afurasi ti wa lahaamọ bayii, gẹgẹ bawọn ṣe n duro de igbẹjọ kootu ti yoo waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Wọn ni loṣu to kọja ni wọn ti kọkọ fi panpẹ ofin gbe Pasitọ Nthenge, ti wọn si foju ẹ bale-ẹjọ, lẹyin tawọn ọmọ meji kan ti wọn wa lakata awọn obi wọn febi panu titi ti wọn fi ku. Ṣugbọn wọn pada yọnda Nthenge, lẹyin ti wọn faaye beeli ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ṣile, (Shilling) owo ilẹ Kenya, silẹ fun un, eyi to ṣe deede pẹlu ẹẹdẹgbẹrin dọla ($700).