Pasitọ ijọ Ridiimu wọ gau, obinrin to fẹẹ fipa ba lo pọ lo pariwo sita

Kazeem Ọlajide

Lojiji ni ọdọmọbinrin tiṣẹlẹ ifipabanilopọ ṣẹlẹ si pẹlu pasitọ ijọ Ridiimu kan lọdun 2006 gba ori ẹrọ abẹyẹfo (twitter) ẹ lọ, nibẹ gan-an lo kọ ọ si  pe, pasitọ kan taẁọn eeyan n pe ni eeyan Ọlọrun, afipabanilopọ ni.

Ọmọbinrin to pe orukọ ara ẹ ni Beatrice Wealth ṣalaye pe ẹni to fẹran ere idaraya bọọlu alapẹrẹ daadaa loun, ati pe ere idaraya yẹn gan-an lo gbe oun de ọdọ pasit̀ọ ti wọn n pe ni Paul Bankole yii lọdun 2016. O ni ọkunrin ọhun naa ni oludari ẹka ere idaraya fun ijọ Ridiimu.

Ọmọbinrin yii fi kun ọrọ ẹ pe oun ko ju ọmọ ogun ọdun lọ nigba naa, ọrẹ oun kan lo si juwe pasitọ naa foun pe o n ṣa awọn ọmọ keekeeke jọ, ti wọn yoo lọọ gba bọolu alapẹrẹ lorilẹ-ede Tokyo.

O ni nnkan to gbe oun de ṣọọṣi Ridiimu niyẹn o, ṣugbọn lẹyin ti baba naa foju kan oun ninu ọọfiisi ẹ, niṣe lo di mọ oun, to ni ki oun jokoo sori ẹsẹ ẹ, to tun fi tipa fẹnu ko oun lẹnu.

Beatrice ni oun jajabọ lọjọ naa, ṣugbọn iṣẹlẹ naa fẹẹ sọ oun di alaigbagbọ nitori oun ko lero pe ẹni to jẹ ojiṣẹ Ọlọrun le hu iru iwa bẹẹ, ati pe agbalagba to ti le ni ọgọta ọdun ṣe le waa ki iru oun mọlẹ bẹẹ.

Ki i ṣe Pasitọ yii nikan lọmọbinrin yii darukọ o, bakan naa lo sọ ti olukọ rẹ kan nileewe Yaba Tech, Dokita Ọdunlade Adekọla, lo pe oruk̀ọ ẹ, o lọkunrin yẹn naa, afipabanilopọ ni, ati pe ọpọ igba gan-an loun ti fidi-rẹmi ninu awọn iṣẹ to n kọ oun nigba naa, nitori niṣe loun maa n sa fun un latigba toun ti mọ ero ọkan ẹ si oun.

Kin ni Beatrice gbe ọrọ yii sori twitter ẹ si, niṣe lawọn eeyan bẹrẹ si ki i, ti wọn si n yin in, bẹẹ lawọn ọmọleewe ẹgbẹ rẹ tawọn naa ti ni irufẹ iriri bẹẹ bẹrẹ si i darukọ awọn olukọ mi-in nileewe ọhun tawọn naa jẹ afipabanilopọ.

Ṣa o, awọn ijọ Ridiimu naa ti gbe igbesẹ lori Pasitọ Paul Bankole to sọrọ rẹ yii, bẹẹ ni wọn ti ke si oun paapaa lati yọju, ko le ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn.

Abikẹ Dabiri-Erewa naa ti ki i ku igboya to ni, bẹẹ lo jọ pe ọrọ ọhun ṣẹṣẹ n bẹrẹ ni pẹlu bi orukọ oriṣiiriṣii ṣe n jẹ jade bayii.

 

Leave a Reply