PDP Ogun le Ladi Adebutu atawọn mẹrin mi-in ninu ẹgbẹ wọn

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ko jọ pe wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun ti i rodo lọọ mumi o, ọrọ naa ti di egbinrin ọtẹ, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru. Eyi ko sẹyin bi ẹgbẹ yii ṣe tun kede ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe awọn ti le oludije fẹgbẹ wọn ninu eto idibo gomina ti kootu yọ laipẹ yii, Ladi Adebutu, atawọn mẹrin mi-in, Taiwo Akinlabi, Sunday Solarin, Kayọde Adebayo ati Akinloye Bankọle danu ninu ẹgbẹ naa.

Wọn ni lẹyin ti igbimọ ẹlẹni marun-un, eyi ti Họnọrebu Akintunde Mufutau, jẹ alaga rẹ, ti ẹgbẹ gbe kalẹ lati ṣewadii awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan naa jabọ iwadii wọn ni wọn gbe igbesẹ lati le wọn danu.

Awọn ẹgbẹ ọhun ni ṣiṣe awọn ohun to lodi si ofin ẹgbẹ, aile ko ara ẹni nijaanu, iyapa ati awọn iwa to le ba orukọ ẹgbẹ naa jẹ ni awọn eeyan wọnyi hu. Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan Adebutu pe o ṣe arọnda ronda orukọ awọn aṣoju ti wọn kopa ninu idibo abẹle lati yan awọn ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn lasiko idibo ọdun to n bọ, eyi to waye ninu oṣu Karun-un, ọdun yii.

Alaga igbimọ iwadii yii sọ pe, ‘‘Lẹyin gbogbo iwadii wa lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn yii, ijokoo yii ri i pe Adebutu atawọn mẹrin yii jẹbi. A mu aba wa pe ki wọn le wọn kuro ninu ẹgbẹ, bẹẹ la ti kọwe si awọn ẹka gbogbo to yẹ ti yoo mu igbesẹ naa ya kankan.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni awọn oloye ẹgbẹ PDP yii kan naa nipinlẹ Ogun kede pe awọn ti yọ Jimi Lawal ti ile-ẹjọ ni oun lo yẹ lati dupo gomina lorukọ ẹgbẹ naa ninu ibo ọdun to n bọ ninu ẹgbẹ.

Igbesẹ yii lawọn naa ni ko sẹyin abọ iwadii awọn igbimọ tawọn gbe kalẹ lati ṣagbeyẹwo awọn ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa. Lara ẹ ni pe o ṣeto idibo abẹle ti ko bofin mu. Lara awọn ti wọn jọ le ninu ẹgbẹ pẹlu Lawal ni Muyiwa Ọdẹbiyi, Mọrufu Olajide ati Ademọla Odoye

 

Leave a Reply