Faith Adebọla
Aarẹ ilẹ wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari ti sọ pe bawọn ajagunta Taliban ṣe gbajọba orileede Afghanistan lọjọ Aiku, Sannde, ti fihan pe ilẹ Adulawọ ti wa ninu ewu, tori awọn apanilaya ati afẹmiṣofo le bẹrẹ si i gbogun ti ilẹ Adulawọ pẹlu irọrun, ki wọn si sọ ilẹ wa di ibi-ijẹ wọn.
Buhari sọrọ yii ninu apilẹkọ kan to fi ṣọwọ si iweeroyin Financial Times of London, lọjọ Aiku.
Buhari ni wahala ti arun Koronafairọọsi mu ki awọn afẹmiṣofo atawọn eeṣin-o-kọ’ku gbilẹ, ki wọn si nayẹ, eyi lo fa a ti awọn Taliban fi le ṣẹgun ijọba awa-ara-wa to wa lori aleefa nilẹ Afghanistan, ti wọn si gbakoso ilẹ ọhun.
O tẹnu mọ ọn pe loootọ l’Afrika le ṣẹgun awọn apanilaya ti wọn n halẹ mọ aabo kaakiri aye yii, ṣugbọn ija naa ki i ṣe ti Afrika nikan, gbogbo aye lo gbọdọ da si i.
“Awọn eeyan gbagbọ pe bi orileede Amẹrika ṣe kẹru wọn kuro ni Afghanistan, boya ija lodi si awọn eeṣin-o-kọku ti dinku ni, ṣugbọn niṣe lawọn eeyan buruku yii tubọ n halẹ mọ ilẹ Afrika, wọn o si jẹ ki ọpọ wa ri oorun sun dọkan. Iru ohun to ṣẹlẹ ni Afghanistan yii lo n waye ni orileede Mozambique, nilẹ Afrika, nibi, gbogbo aye lo si yẹ ko maa da si i, ṣugbọn wọn o ṣe bẹẹ.
Boko Haram ṣi n gbogun ti Sahel, lẹyin ogun ọdun, wọn o ti i bori wọn, ogun ọdun si ree ti Somalia naa ti n ba awọn afẹmiṣofo al-Shabaab fa a. Ọpọ orileede ilẹ Afrika lo n koju akọlu awọn afẹmiṣofo gidi.”
Ṣe, lati ọpọ ọdun sẹyin ni nnkan o ti fara rọ lorileede Afghanisgtan, paapaa latigba ti orileede Amẹrika ti doju sọ wọn fun akọlu to waye ni lọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2001.
Ṣugbọn oṣu to n bọ yii ni Aarẹ Amẹrika, Joe Biden, kede poun maa ko eyi to ṣẹku ninu awọn ọmoogun Amẹrika kuro lorileede Afghanistan.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, niroyin gbode kan pe Aarẹ orileede naa, Ọgbẹni Ashraf Ghani, ti foru boju sa lọ nigba to fura pe awọn ọmọọgun afẹmiṣọfo to n ṣoro bii agbọn maa bori awọn ọmoogun ijọba. Bakan naa lawọn araalu, awọn ajoji, atawọn mọlẹbi Aarẹ ti fibẹru sa kuro lorileede ọhun, gbogbo naa ni iyipada to waye yii ko jinnijinni ba.
Lasiko yii, awọn ọmoogun Taliban ti balẹ siluu Kabul, ti i ṣe olu-ilu orileede ọhun, Ọgbẹni Suhail Shaheen, to jẹ Agbẹnusọ awọn Taliban si ti kede pe awọn maa too ṣeto fun ijọba ọtun lati wa lori aleefa laipẹ.