Ẹgbẹ awọn eeyan ipinlẹ to wa ni Aarin Gbungbun orilẹ-ede yii, Middle Belt Forum, ti bu ẹnu atẹ lu Alagba Reuben Faṣoranti ti i ṣe ọkan lara awọn aṣaaju ilẹ Yoruba fun bo ṣe jẹjẹẹ atilẹyin, to si fọwọ si oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, gẹgẹ bii ẹni ti wọn fara mọ fun ipo aarẹ ọdun to n bọ, wọn ni ilẹ yoo bi i.
Latigba ti apa kan ẹgbẹ Afẹnifẹre ti kede atilẹyin wọn fun Tinubu lasiko tọkunrin naa ṣabẹwo sawọn aṣaaju ẹgbẹ ọhun niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, ni omi alaafia ẹgbẹ naa ti daru, ti nnkan o si fi bẹẹ ṣẹnuure ninu ẹgbẹ wọn mọ.
Alagba Faṣoranti atawọn oloye inu ẹgbẹ wọn o tun waa fi mọ nibẹ, niṣe ni wọn tun ju gomina tẹlẹri l’Ekoo ọhun saarin, ti wọn gbọwọ le e lori, ti wọn si n rọjo adura le e lori pe Ọlọrun yoo gbe e depo naa.
Ontẹ ti wọn jan Tinubu gẹgẹ bii oludije dupo aarẹ ti wọn lawọn fọwọ si yii lo pada bi Ige, to tun bi Adubi, gẹgẹ bi ẹni to jẹ Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Ayọ Adebanjọ, ṣe ko ọrọ naa danu, to si fi ye wọn pe eeyan kan ṣoṣo tawọn fara mọ, tawọn si ti leri lati gbaruku ti ni Peter Obi tinu ẹgbẹ Labour Party, bẹẹ lo fitara sọrọ pe ko si aṣẹ ti Faṣoranti ni lati maa ṣe bii olori ẹgbẹ naa.
Nigba to n ba awọn akọroyin Punch, sọrọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni Aarẹ ẹgbẹ awọn eeyan Aarin Gbungbun orilẹ-ede yii, Middle Belt Forum (MBF), Fogu Bitrus, sọ pe, “Ọrọ to ba ni lọkan jẹ gidi gan-an ni, nitori a ti ro pe awọn adari ẹgbẹ awọn ẹya tabi agbegbe kan ti kọja iwa ojuṣaaju nibi ọrọ ibo tabi nnkan to jẹ mọ ẹlẹyamẹya, agaga ninu ọrọ to ba ti wa lati oke tabi tijọba apapọ, mo ro pe iwọnba lo yẹ ki tiwọn mọ ni.
“Eeyan ta a n pọnle, ta a si to sipo pataki ni Baba Faṣoranti pẹlu ọjọ ori wọn atawọn nnkan mi-in ta a n wo lara wọn. A mọ pe lati bii ọdun meji sẹyin ni wọn ti kuro nipo gẹgẹ bii olori ẹgbẹ ọhun, Baba Adebanjọ la si mọ gẹgẹ bii olori ẹgbẹ naa lọwọlọwọ bayii. Ọrọ buruku to ba ni lọkan jẹ ni bo ṣe waa deede jade to wa ọrọ Ahmed Tinubu mọri, lori eleyii, o da mi loju pe awọn alalẹ yoo binu si i, wọn yoo si bi i, ki i ṣe nitori pe ọtọọtọ loju iwoye wa o, iyẹn gangan kọ nidi. Idi ta a fi ri i bẹẹ ni pe, o maa n ni asiko kan nile aye ẹda, teeyan yoo fọrọ ojuṣaaju ati imọ-tara-ẹni-nikan silẹ, ti yoo si ṣe bii agbalagba lawujọ. Mo fẹ ko tun ọrọ yii da ro daadaa”.
Bitrus tẹsiwaju pe oun o ri atilẹyin ati bi Faṣoranti ṣe jan Tinubu lontẹ yii bi irinṣẹ ọwọ awọn oloṣelu lati da aarin ẹgbẹ Afẹnifẹre ru, ki wọn si pin in yẹlẹyẹlẹ, o loun rọ Faṣoranti lati ni arojinlẹ lori boya iwa to hu yẹn le ṣanfaani fawọn ọmọ Naijiria.
Nigba ti wọn bi ọkunrin naa leere boya awọn igbimọ ẹgbẹ MBF ti kede erongba wọn lori oludije dupo aarẹ ti wọn n tẹle, o ni, “A ti sọ ero ọkan wa tẹlẹtẹlẹ. Koda gan-an, ko too di pe wọn dibo abẹle lawa ti sọ pe a o ni i gbe sẹyin oludije dupo to ba ti apa Ariwa ilẹ yii wa, tori a gbagbọ pe asiko awọn eeyan apa Guusu niyi. Bo tilẹ jẹ pe a o bẹnikan ṣ’ọta ninu awọn to fẹẹ dupo aarẹ lati apa Guusu(South) nilẹ yii, Tinubu ti ṣe nnkan ta a ro pe a o le gba laelae.
“Nilẹ Naijiria toni to jẹ pe latara ẹṣin Musulumi la ti n rawọn olubi ati ọdaju ẹda bii Boko Haram, awọn Fulani darandaran, awọn agbebọn atawọn ikọ agbesunmọmi mi-in, nitori bẹẹ lọrọ Musulumi meji yẹn o ṣe le waye, a o tiẹ le tẹwọ gba a. Fun idi eyi, ninu ọrọ to wa nilẹ yii o, Tinubu o tilẹ si ninu awọn ta a le ka kun awọn to yẹ ka gba ọrọ wọn yẹwo, tori a gbọdọ wo nnkan ti yoo ṣe orilẹ-ede yii lanfaani, ki i kan ṣe ka fi ifẹ inu, ojuṣaaju tabi imọtara-ẹni-nikan ṣe e”.
Bakan naa lẹgbẹ awọn eeyan agbegbe Naija Delta, Pan Niger Delta Forum(PANDEF), ṣalaye pe awọn o ti i fontẹ lu oludije dupo aarẹ ọdun 2023 kankan.
Igbimọ ajọ PANDEF ni loootọ lawọn ti ṣepade ranpẹ pẹlu Peter Obi lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, niluu Eko, ṣugbọn awọn yoo ri i daju pe awọn tun ri awọn ondupo aarẹ lati ẹkun Guusu ilẹ yii.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ken Robinson, ṣalaye pe, “A o ti i fẹnu ko lori ọrọ Peter Obi, ajọ PANDEF o ti i fọwọ si oludije dupo aarẹ kankan, ohun tawa kan mọ, ta a si jọ pinnu ninu ẹgbẹ wa ni pe lati apa Guusu ni ki aarẹ wa tuntun ti wa.