Pẹlu ohun to wa nilẹ yii, Tinubu ko le kopa ninu atundi ibo kankan nilẹ yii – Obi

Faith Adebọla

 Oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, LP, Alagba Peter Obi, ti sọ pe pẹlu afojuda ati iṣiro to wa nilẹ tawọn ṣe lori ẹjọ to wa ni kootu, o ni tile-ẹjọ ba fi da idibo to gbe Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu wọle nu, ti wọn si paṣẹ ki atundi ibo waye, Tinubu ko ni i kopa kankan ninu irufẹ atundi ibo bẹẹ labẹ ofin.

Agbẹnusọ fun Obi, to tun jẹ Alukoro ẹgbẹ ipolongo ibo Obi-Datti Campaign Organisation, Ọgbẹni Diran Onifade, lo sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere tiweeroyin Thisday bi i.

Ọkunrin naa sọ pe ki i ṣe pe awọn lọọya Tinubu n tan onibaara wọn jẹ lasan, o ni wọn tun n gbiyanju lati ṣe bojuboju fawọn igbimọ onidaajọ ẹlẹni marun-un ti wọn n gbọ awuyewuye to su yọ nibi eto idibo sipo aarẹ to kọja, iyẹn Presidential Election Petition Court, eyi ti Onidaajọ Haruna Tsammani, ṣe alaga rẹ.

O niṣe loun rẹrin-in iyangi nigba toun gbọ ẹbẹ kan ti ikọ awọn agbẹjọro Tinubu, Amofin agba Wọle Ọlanipẹkun, bẹbẹ rẹ ninu ọrọ asọpari atotonu wọn lọsẹ to kọja pe aibaamọ ti awọn adajọ naa ba pinnu pe ki atundi ibo waye, o ni ki wọn ma ṣe jẹ ki Peter Obi, ti ẹgbẹ Labour Party kopa, laarin oun Tinubu, ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ati Atiku Abubakar, ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ni ki wọn jẹ ki kinni ọhun mọ si.

Tinubu ni idi ni pe awuyewuye naa ko kan ẹni to nipo kẹta, aarin ẹni to gbegba oroke ati ẹni to wa nipo keji ni ofin sọ pe ki irufẹ atundi ibo bẹẹ ti waye.

Amọ Peter Obi sọ lopin ọsẹ yii pe niṣe lawọn agbẹjọro Tinubu fẹẹ maa la le awọn adajọ lọwọ ni, ti wọn si fẹẹ ṣi wọn lọna lati lọ ofin lọrun fun anfaani ara wọn.

O ni: “Ti atundi ibo ba maa waye, aarin awọn meji ti ibo wọn pọ ju lọ lo maa jẹ. Tinubu ko le si lara awọn meji ọhun nitori awọn ẹsun ta a fi kan an ti lagbara to lati mu ki wọn yọ ọ danu, pe ko kunju oṣuwọn latilẹ wa. Ẹsun ayederu iwe-ẹri, ẹsun lilọwọ ati jijẹbi okoowo egboogi oloro, ẹsun yiyan igbakeji rẹ lọna ti ko ba ofin mu ati bẹẹ bẹẹ lọ. Gbogbo awọn ẹsun wọnyi ti kọkọ wọgi le kikun oju oṣuwọn rẹ lati kopa lakọọkọ na.

“Tori ẹ, oun gan-an lorukọ ẹ ko ni i si lori iwe atundi ibo. Gbogbo eyi tawọn lọọya rẹ n ṣe yii ko kọja pe wọn o fẹ ko kọkan soke. Bi wọn ṣe n tan an ni wọn n lugọ sẹyin ika kan fawọn adajọ Tiribuna. Amọ awọn adajọ naa ki i ṣe ope, wọn o si gọ, wọn ri gbogbo ẹjọ ati bi nnkan ṣe lọ.”

Lori bi wọn ṣe ni ipo kẹta ni Peter Obi wa lasiko idibo to lọ yii, ọkunrin naa ni, “a ti ṣalaye bi wọn ṣe ji ibo wa nipinlẹ Rivers ati Benue. Ti wọn ba yọ eyi ti wọn ji kuro ninu tiwọn, ti wọn lẹ ẹ mọ ti Obi, ibo wọn yoo joro gidi ni, ti Obi yoo si roke daadaa. Ẹ jẹ ka wo ohun tawọn adajọ maa ṣe,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply