Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori aṣemaṣe to ṣe pẹlu akẹkọọ obinrin kan to ti kẹkọọ pari bayii nileewe gbogboniṣe The Polyechnic, Ibadan, awọn alaṣẹ ile-ẹkọ naa ti yọ olukọ naa, Ọgbẹni Ajadi Kelani Ojo Ọmọtọshọ kuro lara awọn oṣiṣẹ wọn.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ni wọn fi lẹta iyọniniṣẹ ọhun ranṣẹ si Ọgbẹni Ọmọtọṣọ to jẹ olukọni lẹka ti wọn ti n kọ nipa eto ati agbekalẹ ilu ati agbegbe tuntun (Urban and Regional Planning) lẹyin ti igbimọ to ṣewadii ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an ti da a lẹbi.
Ninu lẹta ọhun, eyi ti akọwe agba ile-ẹkọ giga naa, Abilekọ M.T. Fawale, fi ẹda rẹ ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, lo ti ni iwa àìbójúmu ti Ọgbẹni Ọmọtọshọ hu pẹlu obinrin to jẹ akẹkọọ rẹ tẹlẹ yii jẹ nnkan to ba ileewe naa loju jẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ti o ko ba gbagbe, o lọwọ ninu iwa ibajẹ kan pẹlu ọkan ninu awọn akẹkọọ Poli Ibadan tẹlẹ to gba abẹ rẹ kọja. Iwa buruku ti o hu yii ti ta epo si aṣọ aala akẹkọọ-jade ileewe yii.
“Wa a tun ranti pe o ti fara han niwaju igbimọ oluwadii ileewe yii lori ọrọ naa. Iwadii finnifinni ti igbimọ ọhun ṣe fi han pe o jẹbi ẹsun naa, igbimọ alaṣẹ ileewe yii si ti fọwọ si i pe ka le ẹ danu lẹnu iṣẹ lẹ́yẹ-ò-sokà.
“O ti kuro ni olukọ ileewe yii lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii lọ.”
Awọn alaṣẹ Poli Ibadan waa rọ olukọ ti wọn le danu lẹnu iṣẹ naa lati jọwọ gbogbo dukia tabi ohun gbogbo to jẹ tile-ẹkọ gbogboniṣe naa to ba wa lọwọ ẹ fun olori ẹka ẹkọ rẹ.
Oga o