Poli Ibadan fofin de awọn akẹkọọ lati maa gbe ọkọ ayọkẹlẹ wọnu ọgba ileewe

Ọlawale Ajao, Ibadan
Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun (21), oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, o ti deewọ fawọn akẹkọọ ileewe Gbogboniṣe ti ilu Ibadan (The Polytechnic, Ibadan), lati maa gbe ọkọ ayọkẹlẹ tabi ọkada olowo nla ti wọn n pe ni powerbike’ wọnu ọgba ileewe ọhun.

Nibi ipade ti awọn alaṣẹ ileewe yii ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu yii, ni wọn ti ṣepinnu naa.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Igbakeji oludari ile-ẹkọ giga naa,

Abilekọ F.B Akantade, fi sita lorukọ ọga, o ni akẹkọọ ti ko ba tẹle aṣẹ yii yoo jiya nla labẹ ofin.

Wọn ni to ba si jẹ pe iru ẹni bẹẹ ki i ṣe ọmọ Poli Ibadan, niṣe lawọn yoo fa a le agbofinro lọwọ.

O fi kun un pe “ọkọ ayọkẹlẹ tabi ọkada ti wọn n pe ni power bike ta a ba ri ninu ọgba ileewe yii, a maa gbẹsẹ le e ni, ẹgbẹrun lọna ogun Naira (₦20,000) si lowo itanran ti ẹni to ni in yoo fi gba nnkan rẹ pada’’.

Ṣaaju ikede awọn alaṣẹ Poli Ibadan yii lawọn ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla nla pẹlu oriṣiiriṣii ọkada igbalode ti wọn n pe ni pawa baiki yii ti maa n kun inu ọgba ileewe ọhun fọfọ, to si jẹ pe awọn akẹkọọ ni wọn maa n ni awọn eyi to daa ju lọ ninu awọn nnkan irinṣẹ naa.

Ṣugbọn ṣaa, awọn akẹkọọ ti n kun yunmuyunmu nitori aṣẹ tuntun yii, wọn ni inira lofin naa yoo mu ba awọn.

 

Leave a Reply