Adewale Adeoye
Gbajumọ olorin hipọọpu nni, Habeeb Okikiọla ẹni tawọn eeyan mọ si Portable ti tun bọ sita gbangba lati sọko ọrọ lu gbogbo awọn to n pẹgan rẹ pe ko jẹ nnkan kan. Ninu oko ọrọ to sọ lu awọn ọta rẹ gbogbo lo ti ni ki wọn ma ṣe foju akuṣẹẹ tabi talaka wo oun rara, nitori owe agba kan to sọ pe ‘agba to ba lomi ninu ki i pariwo’ loun tẹle toun ko ṣe pariwo aduru owo ati ile toun ni fawọn eeyan rara.
Ninu fọrọwanilẹnuwo kan to ni pẹlu olootu eto kan lori ẹrọ ayelujara laipẹ yii ni ọba orin Zazu-zeh ti sọ pe, ‘Ẹ ma foju oloṣi wo mi rara, beeyan pe mi ni olowo pọrọku, ko buru rara, aimọye miliọnu Naira lo wa ninu akaunti mi bayii, mo si ti nile to le ni ọgbọn kaakiri aarin igboro ilu Eko ati ipinlẹ Ogun. Mo maa n ṣe itọrẹ aanu nigba gbogbo nitori oke lọwọ afunni maa n gbe, ko sigba ti ma a ṣaanu fawọn to wa nnkan wa sọdọ mi ti mi o ki i ri ilọpo meji rẹ gba pada lọdọ Ọlọrun Ọba. Mi o ni i dawo fifun ni duro rara, nitori pe bi mo ṣe n fọn owo danu fawọn alaini gbogbo, bẹẹ ni ọba oke n ran mi lọwọ gidi.
Iṣẹ orin ti mo n ṣe yii da bii oogun owo ni, igbega ati oriire wa nibẹ daadaa fun mi, afi bii ẹni pe eeyan ṣoogun owo ni bi awọn araalu ba nifẹẹ eeyan tan nidii iṣẹ orin yii. Emi paapaa mo pe bii ẹni ti ko da pe ni mo ṣe maa n ṣe nigba miiran, ṣugbọn mo mọ ohun ti mo n ṣe daadaa, mo nile lagbegbe bii: Abule-Ẹgba, Ikeja, Sango-Ọta, ati Abẹokuta. Mo ṣẹṣẹ tun ra ile kan bayii ni, idi ti mo si ṣe n ra awọn ile naa kaakiri bayii ni pe ko sẹni to mọ ilẹ to maa mọ lọla rara. Mo fẹẹ le sọ pe mo lowo lọwọ ju ọpọ awon ẹlẹgbẹ mi gbogbo lo, awọn kan ninu wọn, igbe aye ẹtan ni wọn n gbe, wọn aa gbe ohun ti ki i ṣe tiwọn sori ẹrọ ayelujara pe awọn lawon ni in. Emi ki i se bẹẹ rara. Ohun ti Ọlọrun Ọba fun mi to mi i gbe igbe aye idẹrun daadaa’.