Posi mẹta, awọtẹlẹ obinrin rẹpẹtẹ ni wọn ba lọwọ babalawo to n ṣoogun fawọn ọmọ yahoo

Adeoye Adewale

Ọlọpaa ilu Abuja ti sọ pe awọn babalawo mẹta kan, Ọgbẹni Uluko Adakwu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), Salisu Aduh, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), pẹlu Amads Halilu, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) tawọn mẹtẹẹta jẹ ọmọ ipinlẹ Kogi, lọwọ awọn ti tẹ. Ẹsun ti wọn tori ẹ mu wọn ni pe awọn ọdaran mẹtẹẹta naa n ṣiṣẹ fun awọn ọmọ Yahoo niluu Jikwoye, lagbegbe Orozo, niluu Abuja.

Alaye ti Alukoro ileeṣe ọlọpaa agbegbe naa ṣe fawọn oniroyin nipa awọn afurasi ọdaran tọwọ tẹ yii ni pe awọn kan to mọ nipa iṣẹ laabi tawọn mẹtẹẹta ọhun n ṣe ni wọn waa fọrọ wọn to ileeṣe ọlọpaa leti, tawọn si lọọ fọwọ ofin mu gbogbo wọn.

Titi di asiko ta a fi n ko iroyin naa jọ ni SP Boko ni awọn ọdọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkanla ati mẹtala lọ tawọn ko ni igbekun awọn ọdaran ọhun ṣi wa lọdọ awọn. Bẹẹ lo ni awọn ti n ṣe iwadii lati mọ ohun ti wọn fẹẹ fawọn ọmọ naa ṣe.

Alukoro ni loju-ẹsẹ lawọn ọdaran mẹtẹeta naa ti jẹwọ pẹ loootọ lawọn maa n ṣiṣẹ fawọn ọmọ Yahoo-Yahoo, ti wọn maa n loogun lati fi gba owo lọwọ awon eeyan (Yahoo Plus) lagbegbe naa, ati pe lẹyin ti wọn ba gba gbogbo owo ọwọ wọn tan, o ṣee ṣe ki won tun pa awọn ẹni ti wọn ba lu nijibi ọhun.

Lara awọn ohun ti SP Boko lawọn ka mọ awọn ọdaran naa lọwọ ni ‘posi tuntun mẹta ti ko seeyan ninu rẹ, oogun oloro, mọto ayọkẹlẹ Toyota Prado kan, mọto ayọkẹlẹ Lexus 330 kan, pẹlu foonu mẹẹẹdogun’.

Bakan naa lo ni awọn tun ri awọtẹlẹ obinrin to pọ daadaa ninu awọn ẹru ofin tawọn ba lọwo awọn ọdaran naa, eyi tawọn ọlọpaa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe lara awọn to ti lugbadi wọn ni wọn ni awọn awọtẹlẹ naa.

Ọga ọlọpaa Ẹka Zone 7, Kayọde Ẹgbẹdokun, waa rọ awọn eeyan agbegbe naa pe ki wọn mọ iru awọn ibi  ti wọn yoo ti maa jọsin lakooko yii, nitori pe onirọ lo pọ ju lode bayii.

Leave a Reply