Posi ni wọn fi gbe Portable lọ sileegbafẹ to ti lọọ kọrin l’Ekoo

Faith Adebọla

Iyanu lọrọ ọmọkunrin olorin taka-sufee to fẹran ijagbọn bii kaa-si-nnkan nni, Ọlalọmi Habeeb, ti gbogbo eeyan mọ si Portable ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to ri fidio ọmọkunrin ti wọn n pe ni Zah Zuh yii bo ṣe gbe ara rẹ sinu posi, to si pe awọn gbokuu gbokuu pe ki wọn waa gbe posi naa lọ sibi to ti fẹẹ kọrin n’Ikẹja. Nigba ti awọn to si gbe posi naa ṣi i, ni Portable ba jade ninu rẹ ganboro.

ALAROYE gbọ pe ile igbafẹ Fẹla to wa n’Ikẹja ti wọn maa n pe ni Ojubọ Fẹla, iyẹn (Fẹla Shrine), ni ọmọkunrin to ti fi tatoo kọ oriṣiiriṣii nnkan sara rẹ yii ti lọọ ṣere fun awọn ololufẹ rẹ, eyi to pe ni Portable Live Concert l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila yii.

Awọn ero ti wa ni gbọngan ti eto naa ti fẹẹ waye, wọn ti n reti ọmọkunrin ti orin rẹ to pe ni Zah Zuh Zeh milẹ titi lọdun to kọja naa ko waa da wọn laraya.

Afi bi wọn ṣe ri awọn to maa n gbokuu to wọle sinu gbọngan naa, gbogbo wọn wọ aṣọ funfun, wọn si gbe posi kan wọle, bẹẹ ni wọn n ju posi naa sọtun-un sosi bi wọn ṣe maa n ṣe nibi eto isinku. N lawọn ero ba n wo ohun to fẹẹ ṣẹlẹ. Afi bi wọn ṣe gbe posi naa kalẹ ti wọn ṣi i, ni ọmọ Ọlalọmi ba jade ninu posi naa ganboro pẹlu igo funfun loju.

Latigba ti aworan naa ti n ja ran-in lori ayelujara ni awọn eeyan ti n sọ ero tiwọn nipa rẹ. Ọpọ eeyan ni inu wọn ko dun si ohun ti ọmọkunrin naa ṣe. Ṣugbọn awọn kan sọ pe o fi n wa okiki ni, wọn ni ko si ohun ti awọn ọmọ ode oni ko le ṣe lati wa okiki.

Lara awọn to ti sọrọ lori bi Portable ṣe de ara ẹ mọnu posi ni oluwa.ti.demilade to sọ pe, ‘ki Ọlamide too kọwọ bọwe fun olorin mi-in, wọn gbọdọ lọọ gba iwe wa lọdọ dokita wọn pe ọpọlọ wọn pe daadaa.’

Ẹlomi-in to tun kọ ọrọ nipa iwa ti Ọlalọmi hu yii ni ebunoluwaagborlor, to kọ ọ pe ‘Idaamu adugbo yin, dajudaju, eleyii ki i ṣe oju lasan’.

Empress Jovita sọ ni tiẹ pe, ‘ere naa ni yoo maa pe ọrọ yii titi to fi maa laju rẹ, to si ama ba ara rẹ lọrun’ .

Ẹni kan ni boya ohun to ṣe to fi di olokiki niyi, awọn ope nikan ni ko mọ.

Tẹ o ba gbagbe, asiko kan wa ti ọmọkunrin olorin to ṣẹṣẹ bimọ laipẹ yii lọ si ilu oyinbo, to si ya posi kekere kan si oju rẹ.

Leave a Reply