Rasaki atọrẹ ẹ n rin ni bebe ẹwọn, ewurẹ ni wọn lọọ ji ko ni Ijan-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọkunrin tẹwọnde kan, Basiru Rasaki, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, pẹlu ẹsun pe o lọọ ji ewure ko ni Ijan-Ekiti.

Bakan naa ni wọn tun mu ọkunrin kan ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan pẹlu ẹsun pe o lọọ ji waya ina kan laduugbo Agric-Ọlọpẹ, l’Ado-Ekiti.

Nigba ti wọn n ṣe afihan awọn mejeeji ni olu ileeṣẹ wọn to wa l’Ado-Ekiti, Ọga agba patapata awọn ẹṣọ Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe Rasaki to ṣẹṣẹ tẹwọn de ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii, lo ti kọkọ sa mọ awọn ọmọ ogun oun lọwọ lọsẹ meji sẹyin pẹlu ankọọbu ti wọn ko si i lọwọ, ki ọwọ wọn too pada tẹ ẹ ni Ijan-Ekiti, nibi to ti lọọ ji ewurẹ ko.

O sọ pe oun atawọn ẹgbẹ rẹ yooku lọwọ tẹ lẹyin ti wọn ti kopa ninu aimọye idigunjale to ti waye nipinlẹ Ekiti, ni pataki ju lọ, ni Ado-Ekiti to jẹ olu ilu ipinlẹ Ekiti.

Nigba to n sọrọ nipa ọdaran miiran ti wọn mu nibi to ti lọọ ji waya ina ka, ọga Amọtẹkun yii sọ pe ọdaran naa to n ṣiṣẹ ina, ni wọn ti n wa lati igba diẹ, ki ọwọ palaba rẹ too ṣegi.

O ṣalaye pe ọdaran ti sọ awọn eeyan ilu Ado-Ekiti ati ilu miiran to yi i ka sinu okunkun ni aimọye igba pẹlu bo ṣe n ji waya ina ka.

O fi kun un pe wọn yoo gbe ọdaran naa lọ sile-ẹjọ lati lọọ foju wina ofin ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ naa.

Leave a Reply