Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, ọṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ni iyawo Oloye Kessington Adebutu ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹbu dagbere faye, Korona ni wọn lo pa a.
Ko si kinni kan to ṣe Iya to bi Tọpẹ Adebutu, iyawo ọmọ Ọbasanjọ tẹ́lẹ̀, gẹgẹ bi ẹka iroyin Street Journal to gbe iroyin yii jade ṣe ṣalaye.
Ojiji ni wọn ni mama naa bẹrẹ si i ri apẹẹrẹ iba ati otutu lopin ọsẹ yii.
Iba naa lo yiwọ biri to fi di pe wọn sare gbe e lọ sọsibitu St. Nicholas, l’Ekoo, ṣugbọn àwọn dokita sọ fun wọn pe oku ni Rosemary ti wọn gbe wa yii, wọn lo ti ku patapata.
Iya to doloogbe yii ni iyawo keji to ku fun Baba Ijẹbu laarin ọdun mẹrin. Ọdun 2017 ni iyawo rẹ kan, Ọlaide Adebutu Abimbọla, jade laye, ki Rosemary naa too tun ṣalaisi bayii.