Ọrẹoluwa Adedeji
Owe Yoruba kan lo sọ pe ka ku lọmọde ko yẹ ni, o san ju ka dagbadagba ka ma ni adiẹ irana lọ. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun Rukayat Gawat, ọdọmọde olorin Musulumi to ku lojiji nni. Beeyan ba jori ahun, bo ba de ile ọkọ obinrin olorin naa, Alaaji Oyefẹsọ, to wa ni adugbo Ọjọta, niluu Eko, ko si ki tọhun ma sunkun. Niṣe ni ero pọ lọ bii omi, tọmọde tagba to wa nibẹ ni ibanujẹ han loju wọn, bẹẹ lawọn mi-in n sunkun kikan kikan. Awọn ẹlẹgbẹ Rukayat ti wọn jẹ olorin Musulumi paapaa bara jẹ gidigidi, niṣe ni wọn si n sunkun kikankikan. Bẹẹ ni wọn n pariwo pe awọn ko jọ sọ ọ bayii. Awọn paapaa jẹrii si i pe o ti rẹ ọmọbinrin naa diẹ tẹlẹ.
Ọwọ aarọ ni ero ti pe si ile ọkọ olorin Islam naa, nibi ti wọn ti kọkọ ṣadura ti wọn maa n ṣe si oku lara fun un. Omilẹgbẹ eeyan lo wa nibi eto naa lati ṣadura fun oloogbe yii. Lẹyin adura yii ni ALAROYE gbọ pe wọn yoo gbe e lọ si ilu ọkọ rẹ ni Ijẹbu-Ayepe, nibi ti wọn yoo sinku rẹ si.
ALAROYE gbọ pe o ti rẹ ọmọbinrin naa diẹ, awọn olorin ẹgbẹ rẹ si jẹrii si i, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to le sọ iru aisan to n ṣe e gan-an. Koda, awọn fọto kan to tẹ ALAROYE lọwọ, ṣugbọn ti o le fun wa lati gbe jade faye ri fi han pe ileewosan kan ni ọmọbinrin naa ku si, bo tilẹ jẹ pe ẹni to sọ fun akọroyin wa ko darukọ ileewosan naa. Sugbọn o han ninu fọto naa pe ọsibitu ni ọmọbinrin yii mi eemi ikẹyin si.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ilu Igbaja, nipinlẹ Kwara ni Rukayat Gawat, ilu Eko ni wọn bii si lọdun diẹ sẹyin.