Ọlawale Ajao, Ibadan
Pátá lásánlàsàn lo da igbeyawo ọdun mẹta ru n’Ibadan pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe fopin si ibaṣepọ laarin awọn ololufẹ naa, Sadia Abass ati Azeez Abass, nigba ti iyawo mu ẹjọ ọkọ ẹ tọ wọn lọ ni kootu Ọja’ba to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, o lọkunrin naa ji pata oun mu ninu ile.
Sadia, ẹni to rọ ile-ẹjọ lati tu igbeyawo awọn ka sọ pe ọpọ igba lọkọ oun maa n fipa ba oun laṣepọ, bẹẹ ki i ṣe ojuṣe ẹ gẹgẹ bii ọkọ lori oun atọmọ kan ṣoṣo ti oun bi fun un.
Obinrin oniṣowo yii ṣalaye pe lasiko ti ija oun pẹlu ọkunrin naa gbona girigiri loun deede wa ọkan ninu awọn pata oun ti ninu ile, oun si mọ daju pe ọkọ oun lo mu un.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti ọkan ninu awọn pata mi dàwátì ninu ile, mo mọ pe oun lo maa mu un nitori mo kuku ti mọ pe ko nifẹẹ mi tẹlẹ, nigba ti mo loyun ọmọ ẹ sinu gan-an, ko tọju mi rara, o fẹẹ fiya jẹ mi pa nigba yẹn. Iyẹn lo jẹ ki n tete bi i leere pe nibo lo mu pata mi lọ nigba to deede dawati ninu ile, o si loun ko mu pata kankan.
“Nigba ti mo gbe e gbona fun un ninu ile ni mo pada ri pata yẹn nibi ti mo ti wa a laimọye igba ti ko si nibẹ. Mo si mọ pe oun (ọkọ ẹ) lo pada lọọ fi i sibẹ nigba ti mi o ba a mu ọrọ yẹn ni kekere.
Ọlọrun nikan lo mọ nnkan ti iba ṣẹlẹ si mi to ba jẹ pe ko da pata yẹn pada. Mi o ti i mọ nnkan to ṣi maa ṣẹlẹ si ọta mi gan-an bayii. Boya oogun owo lo fẹẹ fi pata oluwa rẹ ṣe bẹẹ yẹn.”
Ninu ọrọ tiẹ, Azeez ta ko gbogbo ẹjọ ti iyawo ẹ ro mọ ọn lẹsẹ, o ni nigba ti oun ki i wọ pata to jẹ tọkunrin paapaa, ki loun fẹẹ fi pata obinrin ṣe.
Olujẹjọ paapaa ṣapejuwe iyawo ẹ gẹgẹ bii alakooba obinrin. O lo ti fẹẹ sọ oun di ẹdun arinlẹ pẹlu bo ṣe maa n gbowo lọwọ oun ni gbogbo igba. Bẹẹ si ree, ki i fẹmi imoore han si gbogbo ikẹ ti oun n ṣe fun un naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Iyawo mi ko ro rere ro mi rara. Gbogbo owo to yẹ ki n na lori iṣẹ mi ki n le fi ṣe daadaa laye ni mo maa n ko le e lọwọ. Sibẹsibẹ naa, ibi lo fi n san an fun mi.
“Onirinkurin obinrin ni, ki i wọle lasiko, nnkan bii aago mẹwaa si mọkanla lo maa n wọle lalaalẹ. Ọpọ igba gan-an ni ki i dana ounjẹ to jẹ pe emi ni mo maa n se ounjẹ ti emi pẹlu ọmọ maa jẹ.”
Ninu idajọ ẹ, Oloye Ọdunade Ademọla ti i ṣe olori igbimọ awọn adajọ kootu naa ti fopin si igbeyawo ọlọdun mẹta ọhun.